Lẹ́yìn Ìpọ́njú Náà – fíìmù lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ pẹlu Yorùbá àkọlékè

Watch Video

October 9, 2015

"Ṣugbọn bí olùṣọ́ bá rí i pé ogun ń bọ̀, tí kò bá fọn fèrè kí ó kìlọ̀ fún àwọn eniyan;

bí ogun bá pa ẹnikẹ́ni ninu wọn, ẹni tí ogun pa yóo kú ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀;

ṣugbọn èmi OLUWA óo bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ olùṣọ́ náà." - Esekiẹli :

Ní aarọ kutu ọjọ Iṣẹgun yii, ti i ṣe ọjọ Kọkanla, ọdun 2001.

- Al, owurọ yii mà dara o, abi bẹẹ kọ? Owurọ ìgbà ẹ̀rùn tó wuni ni.

Ni ọjọ Kọkanla osù Kẹsan an ọdun 2001, ayé yípadà. Tí "ilẹ awọn olómìnira naa" sì di

ilẹ́ awọn ẹni-ìgbèkùn. Awọn ará Ilẹ̀ Amẹrika wa tí ó ti fi ìgbà kan ilẹ jẹ ológo ti ta ominira wọn

nitori idaabobo. Sugbọn se gbogbo awọn nnkan yii sàdéédé sẹlẹ ni bí? "Ọjọ Keje oṣu Kejila, ọdun , jẹ́ ọjọ kan tí

a ó máa ranti fún àìnítìjú. Wọn fínnú-fíndọ̀ kọlu Ilẹ Amerika lójijì."

Ọpọlọpọ ibeere ni n sọ kúlúkúlú lọ́kàn eniyan lori isẹlẹ ọjọ naa - ànì ọjọ àìnítìjú naa. Sugbọn ohun kan

ni a mọ̀ daju; ìkọlù tì ò yanilẹnu naa tó wáyé ní ní Pearl Harbour ṣe okunfa fún awọn isẹlẹ kan

tí yoo kúkú sọ gbogbo ayé di oníjọba ayédọ̀kan.

"Orilẹ-ede Japan fi ìwà-ọ̀dàlẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ogun yii. Isẹgun ni àwa yóò fi rẹ́yiǹ rẹ̀."

Ní igbẹyin ogun Agbaye Keji, a dá Àjọ Àpapọ̀ awọn Orilẹ-ede silẹ, eyi tí ó mú ki

gbigbé ìgbésẹ̀ sí sáà ijọba ayédọ̀kan gbéra-sọ ní kiakia. Ogun kọọkan tí a jà n fi igbesẹ kan sún wa mọ ohun ti Bibeli

pè ní "opin ayé." Awọn agbófinró gbe igi dánà nibi gbogbo; tí awọn ọlọpaa

sì mú ètò-ààbò le koko lara awọn eniyan Ilẹ Amẹrika, sugbọn fun awọn tí wọn ní òye

asọtẹlẹ Bibeli, ohun tí yoo sẹlẹ lẹyin eyi kò ní í jẹ́ iyalẹnu.

Ní awọn asiko kan ní ọjọ iwaju, ẹ̀dà Bibeli ti Ọba Jakọbu sọ pe gbogbo eniyan ní orilẹ-ayé ni wọn

máa se é ni dandan funni lati gba àmì kan kí wọn tó lè tà tabi ra ohunkohun. Bí ọrọ-aje wa sì se n dẹnu kọlẹ,

tí imọ ẹrọ sì ti n gbilẹ̀ sí, owó níná n lọ sí opin igbagbe. Òkodoro pé awujọ kò

ní í maa lo owó fun títà ati rírà kò pẹ mọ́ rárá. Àní ó tilẹ ti bẹrẹ bayii. Bí ó tilẹ jẹ pé ọpọ awọn

olórí ẹlẹ́sìn kan kò gbà bẹẹ, awọn ẹni-ibi kan n sisẹ lọ́sàn-án-lóru lati mú Isejọba Ayé-dọ̀tun sẹ. Àwa pẹlu

rí pé igbẹyin ayé ti sunmọ, tí gbogbo ètò sì n kórí jọ fun ifarahan asòdìsí-Krisiti.

Etí wa n gbọ ohùn awọn tí n dojú ofin wa kodò ni Ilẹ Amẹrika, tí wọn sì n se agbatẹru agbekalẹ

agbaye yii. "...ìsejọba ayé-dọ̀tun..."

Ati pẹlu bí gbogbo eyi ti sunmọ etile, fọ́nrán-aworan yii se koko ni akoko yii ju ti tẹlẹ lọ. Satani

n sísẹ labẹnu lati se ìfilọ́lẹ̀ ijọba ayé-dọ̀kan ati ẹ̀sìn ayé-dọ̀kan

ní igbaradi fun asòdìsí-kristi. Ó tilẹ tún ti tan awọn Kristiani ajíyìnrere igbalode jẹ

lati gbagbọ pé a ó gbà wọn kuro lorilẹ aye siwaju ki Ipọnju Nla Náà tó

sẹlẹ. Ẹkọ yii , ti a mọ̀ sí ̂igbasoke siwájú ipọnju naa,” n kọ wa pe Kristi le pada wa ní

igbakugba, ati pe ko ní í sí ami ipadabọ rẹ̀. Nitori itanjẹ yii,

ni ọpọ Kristiẹni fi wa ni aimurasilẹ patapata fun awọn ohun ti Bibeli n kilọ fun wa pe yoo sẹlẹ.

Bi o tilẹ jẹ pe iwe-mimọ sọ kedere ninu Matteu , ati nibomiran pe, igbasoke yoo waye

LẸYIN IPỌNJU NAA ni, awọn oniwaasu olorukọ, awọn ile-ẹkọ Bibeli, ati awọn fiimu tó gbajumọ bi i

"Awọn tó Kù Lẹyin" ti kọ ogunlọgọ pe ki wọn reti pe igbasoke le ṣẹlẹ nigbakugba.

Ati pe ọpọ Kristiẹni ni kò tí ì ka Bibeli parí tan lodindi funrawọn, diẹ ló mọ̀

pe ẹkọ igbasoke siwaju ipọnju naa jẹ itannijẹ tí kò sí ninu iwe-mimọ. Sugbọn tí igbasoke siwájú ipọnju naa

kò bá sí ninu iwe-mimọ, nibo ni ó ti wá?

Oluṣọ-agutan Anderson: Orukọ mi ni Steven Anderson, mo sì jẹ́ oluṣọ-agutan ní Ijọ Faithful Word Baptist

ni ilu Tempe, Arizona, mo sí n ṣiṣẹ iranṣẹ lati kọ awọn eniyan nipa pé igbasoke siwájú

ipọnju naa nitori ó jẹ́ ipo-ironu tí ó dá lori aimọkan,mo sí gbagbọ pe bí

awọn eniyan bá le ri iwe-mimọ, tí wọn sì rí okodoro naa, ko ní í nira fun wọn lati wa

aridaju pe laisi aniani, igbasoke yoo ṣẹlẹ LẸYIN IPỌNJU NAA ni

Oluṣọ-agutan Jimenez: Orukọ mi ni Roger Jimenez. emi sì ni oluṣọ-agutan fun Ijọ Verity Baptist ní

ilu Sacramento, California. Idile Kristiẹni ni mo dàgbà sí, wọn sì fi kọ mi ni gbogbo aye mi pe igbasoke n

siwaju ipọnju naa ni, ti emi kò sì idi kan lati sọ pé bẹẹ kọ ni. Awọn oniwaasu sọ bẹẹ fun wa,

emi naa kuku gba a bi wọn ṣe sọ ọ, sugbọn nigba ti oju mi ṣí sí ẹkọ naa, mo bẹrẹ

sí rí i bí eyi kò ṣe bá iwe-mimọ mu tó, mo sì rí pe a ni lati kọ́

Bibeli kí a sì mú otitọ ibẹ jade.

Oluṣọ-agutan Anderson: Ẹkọ lori igbasoke siwájú ipọnju jẹ́ ohun tí kò sí tẹlẹ. Kò sí ẹri

pe ẹnikan n kọni bẹẹ siwaju ọdun .

Oluṣọ-agutan Jimenez: A ni lati jẹ́ kí ó yé wa pe ọdun ti pẹ ninu it̀àn. Fun ẹgbẹgbẹrun

ọdun lati sáà ti Kristi, a la awọn atunto kan kọja, a gba abẹ́ ẹkọ awọn onimọ-ijinlẹ ninu

Bibeli kan kọja – ohun yoowu ti o ba ṣe tabi tí o kò faramọ pẹlu awọn bí i Martin Luther, tabi

John Calvin, tabi ẹnikẹni wọn, òkodoro ibẹ ni pe ẹgbẹgbẹrun awọn iwe, ẹgbẹgbẹrun awọn akọsilẹ, ẹgbẹrun awọn

arokọ, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awọn iwaasu ló tí jade kí ó tó di ọdun ,

Oluṣọ-agutan Anderson: Mo sì tún n sọ pe kò sí ẹri oniwaasu kankan lati inu ijọ yoowu,

tabi iru ẹsin Kristiẹni yoowu, tí n kọni ẹkọ yii.

Oluṣọ-agutan Jimenez: Tí ẹ bá wo inu iwe, itan, ẹ maa fẹ lati bi ara yin ni ibeere kan,

"Kin gan an ni orírun ẹkọ igbasoke siwájú ipọnju naa?"

Ọ̀mọ̀wé Roland Rasmussen: Ọkan lara awọn abẹnugan ẹkọ igbasoke siwáju ipọnju naa yii ni ọkunrin kan tí orukọ rẹ̀ n jẹ

John Nelson Darby. Ni awọn ọdun inu , ó bẹrẹ kikọ ẹkọ naa ti ó pe ni "igbasoke

ìdákọ́-ń-kọ́." Lẹyin naa ni ó tún gbé ẹ̀dà Bibeli ti ararẹ̀ jade, ninu eyi ti ó

fa awọn ẹsẹ kan yọ lodindi-lodindi, tí ó sì pòrúurù awọn kókó ẹkọ Bibeli kan, tí ó sì tún yí awọn ibi kika

pataki kan tí n sọ nipa ipadabọ Kristi lẹẹkeji sódì John Nelson Darby, tí a mọ̀ sí “Baba ninu awọn

tí n kọni lẹkọọ Ọmọ-tí-ayé-bí-layé-ńpọ̀n”, ṣe agbatẹru èrò-dìmọ̀ rẹ̀ lori igbasoke n siwájú ipọnju naa ní

gbogbo akoko ọ̀rùndún kọkandinlogun. Lẹyin naa sì ni igbasoke n siwájú ipọnju naa di kari-aye

ninu ijọ Onitẹbọmi nigba ti Ile-itẹwe Oxford University ṣagbejade Atọka Bibeli Scofield, tí ó ní arokọ-aarin

tí n ṣe agbatẹru fun ojuwoye igbasoke ìdákọ́-ń-kọ́ tí tí Darby fi n kọni. Awọn àkọsílẹ̀ yii ti mú kí ọpọ

Kristiẹni tẹwọgba ẹkọ yii bi i pe Ọlọrun funraRẹ ló sọ bẹẹ.

Oluṣọ-agutan Anderson: Eṣu ti lo Atọka inu Bibeli Scofield gẹgẹ bí irinṣẹ rẹ̀ ju

Ohunkohun miran lọ lati ṣe agbatẹru ẹkọ igbasoke n siwaju ipọnju naa. O maa fẹ mọ̀

ibi tí ó ti wa? Bí ó ṣe wọ inu ijọ niyi. ibi yii sì ni awọn oluṣọ-agutan ti maa

n rì i. Kì í ṣe lati inu Bibeli ni ó ti wá. Ó sì daju pẹlu pe kì í ṣe lati ẹnu Jesu ni ó ti jade!

Sugbọn lati ẹnu Scofield ló ti jade wa. Awọn akọsilẹ Scofield ló n tọka sí igbasoke siwájú ipọnju naa,

eyi ti n mú kí ẹni ti n kà wọn gbagbọ pe lati inu iwe-mimọ lo ti wa, tí eyi kò sì jẹ bẹẹ

rara. Tí ó jẹ pe nitori ẹ̀dà Bibeli Scofield tí wọn pin kaakiri awọn ile-ẹkọ Bibeli

tí ọpọ awọn oniwaasu kekeeke n kà ẹ̀dà Atọka Bibeli Scofield naa, wọn bẹrẹ sí ní

tẹwọgba ẹkọ igbasoke siwájú ipọnju naa gẹgẹ ododo, tí wọn sì bẹrẹ sí ní waasu rẹ̀.

Ọ̀mọ̀wé Roland Rasmussen: Awọn àròsọ nipa igbasoke ti n bọ lọna yii tún dé ìran ti n bẹ laye ni

bí ogoji ọdun sẹyin nipasẹ fiimu Don Thompson.

Ọ̀mọ̀wé Roland Rasmussen: Awọn itan aláwògbádùn tí Thompson ṣe naa tún kó ipa tó ní apẹrẹ ninu kíkọ́

awọn iran ọ̀dọ́ iwoyi ní ẹkọ yii. Lati igba tí ó ti kọkọ jade, ó lé ni eniyan ọgbọn miliọnu tí ó ti wo "Bì Olè

L’Óru." Ní ọdun , Ile-itẹwe Tim Dalehouse tẹ iwe Tim LaHaye ati Jerry Jenkins tó dá lori

ẹkọ nipa igba ikẹyin "Awọn tó Kù Lẹyin."

Oluṣọ-agutan Anderson: Eyi jẹ itan àròsọ tí n sọ nipa awọn ti n poora, tí kò sì sí

ẹni tí ó mọ ibi tí wọn lọ. Awọn ọkọ n kọlu arawọn; awọn baalu n ja lulẹ nitori

awakọ-ofurufu ti parẹ, ere itage nipa igbasoke siwájú ipọnju naa ti di

ọkan lara awọn iṣẹdalẹ Ilẹ Amẹrika, ti awọn eniyan sì gba a bẹẹ bí otitọ, tí ó sì jẹ́ pé … o jẹ́

fiimu tí kò mọgbọn dání.

Ọ̀mọ̀wé Roland Rasmussen: Fiimu Awọn tó Kù Lẹyin yoo tẹ siwaju lati ma tà lọ tó miliọnu mẹtalelọgọta kaakiri agbaye, tí

iwe mẹrindinlogun keekeeke ti arawọn jade, pẹlu awọn fiimu àgbélẹ̀rọ mẹta kan titi di oni. Sugbọn “Awọn tó Kù Lẹyin” jẹ́

àròsọ lasan. Lati kọ otitọ nipa igbasoke naa, a ni lati bojuwo awọn oju-ewe

Bibeli funrarẹ̀.

Iran Kẹta – Tẹsalonika Kinni ori Kẹrin ati Mateu ori Kẹrinlelogun

Oluṣọ-agutan Anderson: Tẹsalonika Kinni ori Kẹrin jẹ́ ibi-kika pataki julọ nipa igbasoke.

Oluṣọ-agutan Jimenez: Ninu Tẹsalonika Kinni ori Kẹrin, ni a ti fẹ̀rẹ́ rí ẹsẹ tí ó gbajumọ julọ tí a ba n sọ nipa

igbasoke naa.

Oluṣọ-agutan Anderson: Enikẹni yoo gba pe ibi-kika yii n sọ gẹlẹ nipa igbasoke ni. Eyi jẹ́

ibi ẹkọ tó mọ́ gaara julọ ninu Bibeli nipa bíbọ̀ Jesu ni awọ sanma, ati bí a sì ti maa gbe wa

pade rẹ̀ papọ loke. Bibeli sọ ninu ẹsẹ :

( Tẹsalonika :) "Ẹyin ara, awa kò fẹ́ ki ẹ mà nì òye nipa awọn ti

wọn ti sùn, kí ẹ má ba à banujẹ bi awọn ti kò ní ìrètí."

( Tẹsalonika :) "Nitori tí a bá gbagbọ pe Jesu kú, ó sì jinde, bẹẹ gan an ni

Ọlọrun yoo mú awọn ti wọn ti kú ninu Jesu wà pẹlu rẹ̀."

Oluṣọ-agutan Anderson: Nitori naa, ohun ti ó n sọ nibi ni pe oun kò fẹ kí wọn jẹ aláìlóye

nipa awọn Kristiẹni, awọn ẹni-igbagbọ ti wọn ti kú, awọn ti wọn sùn ninu Jesu, awọn ti wọn ti

lọ wà pẹlu Oluwa. Ó sọ pe, Emi kò fẹ kí ẹ má ni òye awọn ará-ninu-Oluwa yii

nitori pe emi kò fẹ kí ẹ ṣọ̀fọ̀ bí awọn ti kò ni ìrètí. Mo fẹ ki ẹ mọ̀ pe

ẹ maa rí awọn ayanfẹ yin pada, ti wọn jẹ́ ẹni-irapada. Ẹ maa tún wọn rí

lẹẹkan sí i nitori Bibeli sọ pe nigbati Jesu Kristi ba pada dé, ó maa ko wọn

pada pẹlu rẹ̀. Awọn oku ninu Kristi kọkọ maa jinde,

:

( Tẹsalonika :) Ẹ maa fi ọ̀rọ̀ wọnyi tu ara yín ninu .

Oluṣọ-agutan Anderson: Idi ni yii tí eyi fi jẹ iwaasu tí ó gbajumọ julọ ti a n gbọ nibi isinku.

Ọpọlọpọ isinku ni mo ti lọ nibi ti awọn eniyan n fi awọn ọrọ yii tu arawọn ninu. Tori naa, kiyesi

ninu ẹsẹ kọọkan, tó n jẹyọ ni o n mu kí otitọ naa jade pe a maa rí awọn eniyan yii pada,

àní awọn ti wọn ti lọ.

( Tẹsalonika :) Nitori a n ṣọ ọrọ yii fun yin gẹgẹ bi ọrọ Oluwa, pe awa ti a

bá wà laaye. tí a bá kù lẹyin nigba ti Oluwa ba farahan, kò ní siwájú

awọn ti wọn ti kú.

( Tẹsalonika :) Nitori nigba ti ohùn àṣẹ bá dún, olórí awọn angẹli yoo fọhun,

fere Ọlọrun yoo dún Oluwa funrarẹ̀ yoo sọkalẹ lati ọ̀run. Awọn oku ninu Jesuni yoo

kọ́kọ́ jinde.

( Tẹsalonika :) A óo wá gbé awa ti ó ti kú lẹyin, tí a wà laaye, lọ pẹlu wọn ninu awọsanma,

lati lọ pade Oluwa ní ofuurufu, a òo sì maa wà lọdọ Oluwa laelae.

( Tẹsalonika :) Ẹ maa fi ọ̀rọ̀ wọnyi tu ara yín ninu.

Oluṣọ-agutan Anderson: Tori naa, tí òye ọrọ naa bá ye ọ, itunu naa ni pe o maa rí awọn ayanfẹ rẹ

lẹẹkan sí i. Ó sọ pe o maa pada rí wọn nitori pe tí o bá gbagbọ pe Jesu kú, tí

ó sì jinde pada, bẹẹ gelẹ (ní ọna kan naa), awọn oku ninu Jesu ni Ọlọrun yoo mú pada wá

pẹlu rẹ̀. A ó ji wọn dide. Awọn oku ninu Kristi maa kọkọ jinde. Ó sọ pe

Ẹ maa fi ọ̀rọ̀ wọnyi tu ara yín ninu. Kò sí ibikan kan tí a ti sọ ọrọ itunu tí n sọ pe

o kò ní í la ìnilára kọja. Pé wọn kò ní í ni ọ lara. Pé o kò ní í la

ipọnju kọja. Pé o kò ní í la ailera kọja. Pé o kò ní jìyà rara. Ṣé

ibi-kíkà yii tilẹ mẹnu ba ipọnju bí? N jẹ ó tilẹ sọ nnkankan nipa ipọnju bí?

Rara o. Kò ṣọ pe, Ẹ tu ara yin ninu kí ẹ má ba à la ipọnju kọja.Ẹ tu ara yin ninu

Pé kí ẹ tu ara yin ninu kí wọn má ba à ni yin lara. Pé kí ẹ tu ara yin ninu kí ẹ má ba à la igbasoke

siwáju ipọnju kọja. Kì í ṣe ohun tí ó n sọ niyẹn o!

Oluṣọ-agutan Jimenez: Ní bayii, ti a ba yẹ ibi-kika yii wò, awọn àrímọ́ kan nbẹ tí a lè

rí nipa igbasoke tí ó lè ran wa lọwọ lati dá igbasoke mọ̀ ni awọn ibi-kika miran. Mo maa fẹ

ki ẹ lóye ohun tí ó rọ̀mọ́ igbasoke naa. Ti ẹ ba wo ẹsẹ nibẹ,

ó sọ pé, "Oluwa funrarẹ oo sọkalẹ lati ọrun..." Tori naa, ohun akọkọ tí a nilo

lati lóye igbasoke naa ni pe Oluwa n sọkalẹ bọ lati ọ̀run pẹlu ariwo

ati pẹlu ohùn angẹli nla naa, ti mo sì fẹ́ kí ẹ ṣakiyesi eleyii, "fèrè

Ọlọrun yoo sì dún." Eyi ni àrímọ̀ keji tí mo fẹ́ kí ẹ rí nipa igbasoke naa.

Oluwa yoo sọkalẹ wa, fèrè Ọlọrun yoo dún lẹyin naa sì ni Bibeli sọ pe, "Awọn oku

ninu Kristi yoo kọkọ jinde. Lẹyin naa ni awa ti a wà laaye, ni a màa..." Kiyesi

awọn ọrọ yii, " lọ pẹlu wọn ní awọsanma..." Tori naa, nigba ti igbasoke naa ba sẹlẹ,

gẹgẹ bi Tẹsalonika orí ti sọ, awọn àrímọ̀ igbasoke naa ni:

. Oluwa Sọkalẹ . Fere Dún . Lọ pẹlu wọn ní Awọsanma

Oluṣọ-agutan Jimenez: Awa yoo lọ pẹlu rẹ̀ ní awọsanma.

Oluṣọ-agutan Anderson: Pada sí Mateu kí o sì rí hóró-ìtumọ̀ gẹlẹ ní Mateu :-.

Iwọ wo Mateu :, "Lẹsẹkẹsẹ lẹyin ipọnju ọjọ wọ̀n-ọn-nì, nigba miran ẹ̀wẹ̀,

mo maa n fẹ bi awọn eniyan leere pe, "Apá ibo LẸYIN NAA ni kò ye yin gan an ná?"

Sugbọn ó sọ pe:

(Matthew :) "Lẹsẹkẹsẹ lẹyin ipọnju ọjọ wọ̀n-ọn-nì, òòrùn oo sokunkun,

oṣupa kò ní tan imọlẹ rẹ̀, awọn irawọ yoo jábọ́ lati ọ̀run. Gbogbo awọn agbára

tí ó wà ní ọ̀run ni a ó mì jìgìjìgì:

(Mateu :) Àmì ọmọ eniyan yoo wá yọ ní ọ̀run. Gbogbo awọn

ẹ̀yà áye yoo figbe ta, wọn yoo rí ọmọ eniyan ["Ọmọ eniyan"

jẹ́ ohun kan tí Jesu maa n pe ara rẹ̀ nigba ti ó n bẹ lórílẹ̀ ayé] n bọ̀

lori ìkùukùu ní ọ̀run pẹlu agbara ati ogo nla.

(Mateu :) Yoo wa rán awọn angẹli rẹ̀ pẹlu fere nla, wọn yoo

kó awọn ayanfẹ jọ lati igun mẹrẹẹẹrin ayé; ànì lati ìkangun kan dé ìkangun keji.

Oluṣọ-agutan Anderson: Gbogbo awọn hóró-ìtumọ̀ kan naa! Jesu n bọ̀ ní àwọ̀sánmà. Fere kan dún.

Ó rán awọn angẹli rẹ̀ lati kó awọn ayanfẹ jọ

Oluṣọ-agutan Jimenez: Idi ti mo fi fi eyi hàn yin ni pé mo fẹ kí ẹ ni òye pe ninu

Mateu :-, a rí igbasoke naa, a sì fi ṣe àkàwé pẹlu Tẹsalonika :-,

wọn ṣe deedee pẹlu arawọn.

Oluṣọ-agutan Anderson: Fi ìka rẹ há ibẹ yẹn, kí o sì lọ sí Maaku . Bayii, Maaku naa pẹlu kúkú n sọ

ohun kan naa tí Mateu n sọ ni. Eyi ni a n pe ni "ibi-kíkà afẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́". Iwọ

yoo rí iwaasu kan naa, ikọ́ni kan naa, ní awọn ibi-kika mejeeji naa. O le fi wọn

ṣí ẹ̀gbẹ́ arawọn. Ohun kan ni wọn n sọ. Jẹ́ kí n fi hàn ọ nibi ibi-kika yẹn. Ó sọ ní

ẹsẹ :

(Maaku :) Sugbọn ní ọjọ wọnyii, lẹyin ipọnju naa, òòrùn yoo sóòkùn,

oṣupa kì yoo si fi imọlẹ rẹ̀ hàn,

(Maaku :) Awọn irawọ oju ọrun yoo ja silẹ, ati agbara ti n bẹ ni ọrun ni a ó

sì mì tìtì.

(Maaku :) Nigba naa ni wọn ó sì rí Ọmọ-eniyan ti yoo maa ti ọ̀run bọ̀. oun pẹlu agbara

ati ògo,

(Maaku :) Nigba naa ni yoo sì ran awọn angẹli rẹ̀, yoo sì kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ̀ lati

origun mẹrẹẹrin ayé jọ, lati ìkángun ayé títí dé ìkángun ọ̀run.

Oluṣọ-agutan Anderson: Níbi tí a dé bayii, a le gbadura kí a sì maa lọ sílé. A kàn le

pa Bibeli wa dé, kí a sì sọ pé, "Ṣebí ẹ ti rí i bó ṣe rí, ẹyin ará. LẸYIN IPỌNJU NAA ni o," kí

ẹ sì pa Bibeli yin dé, ki ẹ maa lọ sílé. Sugbọn rara o, a kò ní pa Bibeli wa dé, kí

a kọri sílé nitori mo maa fi idi rẹ̀ mulẹ, mo sì maa fihan yin pe igbasoke naa ni

eyi n tọka sí, pé LẸYIN IPỌNJU NAA ló maa ṣẹlẹ.

Ìran - Kì í ṣe awọn "Júù" ni Mateu n sọrọ bá

Oluṣọ-agutan Anderson: Ọpọlọpọ ni yoo tako orí yii ti wọn a sọ pé "O kò lè rí ẹkọ yii kọ

lati Mateu nitori "awọn Júù" nìkan ni Mateu n sọrọ bá. Wọn maa

maa da ibi-kika yii nù ni,won maa sọ pe, Oh, awọn Juu nìkan ni ó wà fún, Awọn onimọ-ijinlẹ Bibeli

kan nibi kan pinnu pe awọṅ ẹya Júù nikan ni iwe Mateu wà fún, tí iwe Maaku wà fún awọn ara

Romu, iwe Luku wà fún Gíríkì, tí iwe Johanu sì wà fún gbogbo ayé, Oh.

o ṣeun o, Oluwa, pe o fi ọ̀kan lara awọn iwe iyinrere fún awa naa! Sugbọn ta ló gbé irú

àfinúrò yii jade? Pe boya iwe nitori awọn Júù ni a ṣe kọ iwe Mateu. Tabi nitori awọn Gíríkì ni a ṣe kọ iwe Luuku.

Tabi boya awọn ara Efesu ni episteli Pọọlu sí awọn ara Efesu wà fún. Kinni iwọ èrò tìrẹ?

Pe boya awọn Heberu ni episteli Pọọlu sí awọn Heberu wà fún. Boya awọn ara

Boya awọn ara Tẹsalonika ni episteli Pọọlu sí awọn ara Tẹsalonika wà fún, ni temi o, emi ni gbogbo awọn ileri

inu iwe naa wà fun! Ori kọọkan, ẹsẹ kọọkan, ìlà kọọkan! Iwe Titọọsi kí ì kúkú ṣe fun Titọọsi nikan!

Iwe kekere kan niyẹn! Gbogbo awọn oluṣọ-agutan ni a kọ ọ fún. Gbogbo

onigbagbọ ní kí ó kà á. Majẹmu tuntun niyẹn!

Oluṣọ-agutan Anderson: Sugbọn ohun tí wọn yoo sọ niyi, "Bí ó ṣe rí kọ́ niyẹn, Oluṣọ-agutan Anderson, kò ye yin ni.

Gbogbo iwaasu yii nipa awọn Júù ni, sí awọn Júù, ati fún awọn Júù. Jesu Krisiti

waasu fun awọn Júù ninu Àròyé lori Oke Olifẹti (eyi ni orukọ inagijẹ tí wọn fun

ibi-kika naa). Oluṣọ-agutan Anderson, awọn Júù ló n bá sọrọ! Ṣé o kò ri bẹẹ ni! Nigba ti ó sọ

ninu Maaku :, Lẹyin ipọnju naa, lẹyin naa ni ó sọ nipa Jesu n bọ̀ láwọ̀sánmà

ni ẹsẹ , ati kíkó awọn ayanfẹ jọ ni ẹsẹ , lati opin ayé,

títí dé opin ọ̀run, eyi ni ohun tí awọn kan n pè ní "awọn Júù nikan ni ó n bá sọrọ." Ó dara, ẹyin ẹ wo

ẹsẹ tó kẹyin ni Maaku : Ohun ti mo n wí fun yin yii, awọn Júù nikan ni mo n wí i fún: ẹ maa ṣe jẹ́ kí

oniwaasu kankan sọ fún yin pé eyi wà fún gbogbo awọn onigbagbọ o. Awọn Júù nikan ló wà fún. Njẹ

ohun ti Bibeli sọ ní Maaku : niyi bí? Rara o. Ó sọ pe

(Maaku :) "Ohun ti mo n wí fun yin ni mo n wí fún gbogbo eniyan: ẹ maa sọ́nà.".

Oluṣọ-agutan Anderson: Gbolohun tó gbẹyin ní orí naa niyi.

(Mark :) "Ohun ti mo n wí fun yin ni mo n wí fún gbogbo eniyan: ẹ maa sọ́nà."

Oluṣọ-agutan Anderson: Sibẹ awọn eniyan sì tun n sọ pe, "Orí yii kò

bá gbogbo eniyan wí. "Awọn Júù nikan ni ó n báwí." Àfi bí i pé ó ti mọ̀ pé

awọn eniyan maa sọ bẹẹ ni, ni ó fi sọ ọ́ ní igbẹyin ibi-kika yii. Gbogbo

eniyan ni mo n bá sọrọ nigba ti mo sọ pé Ẹ maa sọ́nà. Gbogbo eniyan ni eyi wà fún. Lati sọ pe awọn Júù nikan

ibi-kika yii nbáwí panilẹrin. Nigba ti ó sọ ọ gbagada pé

(Mark :) Ohun ti mo n wí fun yin ni mo n wí fún gbogbo eniyan: ẹ maa sọ́nà.

Oluṣọ-agutan Jimenez: Ní ọpọ igba, awọn eniyan yoo wo Mateu :-, wọn yoo sì sọ pe, "Kò buru,

bi o tilẹ jẹ pe ó jọ igbasoke naa, bi o sì tún jẹ́ pe ó n fọhùn bí igbasoke naa, kì í

ṣe igbasoke naa," idi tíwọn sì fi maa sọ pe kì í ṣe igbasoke naa nìyí

tí ẹ bá wo ẹsẹ , ó sọ pe, "Yoo sì rań awọn angẹli rẹ̀ pẹlu ohùn ìpè nla,

wọn o sì kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ̀ lati orígun mẹrẹẹrin ayé jọ, …" awọn eniyan yoo sì wo

ọrọ naa, wọn sì maa sọ pe, "Ṣe ẹ ri bẹẹ, ọrọ naa 'ayanfẹ' kì í ṣe fun awa Kristiẹni o." Wọn a sọ pe,

"Awọn ọmọ Israẹli ni 'ayanfẹ' Tori idi eyi, Mateu kọ ni igbasoke naa. Kì í ṣe fún

awa Kristiẹni. Awọn Júù ni gbogbo ori naa wà fún nitori tí ó n ṣọ nipa awọn ayanfẹ"

Kókó ọrọ ibi ni pe: kí a gba Bibeli laaye kí ó tumọ ararẹ.

Oluṣọ-agutan Anderson: Mo ní iye ìgbà tí Bibeli ko ọrọ naa "ayanfẹ" A kò ní wulẹ̀

ni lati ka gbogbo rẹ̀ nitori kò sí àkókò, sugbọn mo le sọ gbogbo awọn igba tí a lo "ayanfẹ"

mo sì tun le fihan yin pe nígbà kọọkan ti ó wáyé,

awọn tí a gbala ni ó n tọka sí.

Oluṣọ-agutan Jimenez: Idi naa tí awọn eniyan fi rò pe awọn Júù ni ọrọ naa "ayanfẹ" n tọka sí, tabi awọn

"awọn ọmọ Israeli," ní n sọ ni pe, eyiti wọn fi maa ṣe àṣàrò lori Bibeli wọn, eyití wọn maa ka Bibeli wọn

awọn àlàyè inu Bibeli ni won n kà, wọn sì ti tun maa n ka awọn iwe tí ti ọwọ awọn eniyan kọ,

tí awọn eniyan yii sì ti sọ ohun tí "ayanfẹ" jẹ fun wọn. Atọka Bibeli Scofield

ní arokọ kan lori Mateu tí ó sọ pe ọro naa "ayanfẹ" n tọka sí "Israẹli." Sugbọn

Bibeli fúnrarẹ̀ sọ tumọ ararẹ̀, tí Bibeli sì fun wa ní idahun sí awọn ibeere lori awọn ẹkọ naa

tí a ní, ti ẹ bá ṣe àsàrò nipa rẹ̀ ninu Bibeli, ọrọ naa "ayanfẹ" kò tọka si awọn Júù nikan

Oluṣọ-agutan Anderson: Lati tanná sí ọrọ naa ní kíá fun yin, ní Awọn ara Tẹsalonika :, ó sọ pe:

( Thessalonians :) Nitori pé awa mọ yíàn yin, ará, olufẹ ti Ọlọrun;

Oluṣọ-agutan Anderson: ...ó n bá Awọn ara Tẹsalonika sọrọ tí wọn jẹ awọn Keferi. A rí i ninu iwe Awọn ara Romu

:

(Awọn ara Romu :) Tani yoo ha ka ohunkohun sí ọrùn awọn ayanfẹ Ọlọrun? Ọlọrun ní n dáre.

Oluṣọ-agutan Anderson: Ninu ibi mẹrindinlogun ti Bibeli ti lo ọrọ naa "ayanfẹ", mẹwaa ninu wọn ni n sọ

nipa awọn onigbagbọ lapapọ, meji ninu wọn n tọka si awọn onigbagbọ tí wọn jẹ́ Keferi ní pàtó,

ọkan ninu wọn n tọka si awọn onigbagbọ tó jẹ́ Júù meji n tọka si Jesu Kristi funrarẹ̀,

ọ̀kan n tọka si Jakọbu, gẹgẹ bí ẹnikan, tí Ọlọrun yàn. Mo maa fun yin ní ẹsẹ

kan tí ó sọ ọ́ kedere pé ayanfẹ kì í kàn ṣe fun "Israẹli" nitori awọn eniyan sọ pe,

"Awọn ayanfẹ naa? Awọn ọmọ Israẹli ni. Awọn Júù ni."

(Romans :) Ki ha ni? Ohun tí Israẹli n wá kiri, oun naa ni kò rí; sugbọn awọn ẹni-ìyànfẹ́

ti rí i, a sì ṣé àyà awọn yooku le.

Oluṣọ-agutan Anderson: Tori eyi, Bibeli sọ pe, Israẹli kò rí; awọn ẹni-ìyànfẹ́ ti rí i. Bí ó bá jẹ́ bẹẹ, bí Israẹli

bá jẹ́ ẹni-ìyànfẹ́, eyi kò mú ọgbọn kankan lọ́wọ́.

Oluṣọ-agutan Jimenez: Ó hàn kedere kaakiri inu iwe-mimọ, tí ẹ bá gba Bibeli laaye kí ó ṣàlàyé

ararẹ̀, pé kì í ṣe awọn Júù ni "ayanfẹ" naa, pé kì í ṣe orilẹ-ede Israẹli ní "ayanfẹ",

awọn tí-a-gbàlà ní ayanfẹ. Wọn le wa lati ilẹ Asia; wọn le jẹ́ ẹ̀yà Gírìkì, wọn le jẹ́

kògbédè, wọn le jẹ́ ẹ̀yà yoowu. Tí o bá ti gbé Kristi wọ̀, tí o bá ti gbé ẹni tuntun

wọ̀, ayanfẹ ni o jẹ́. Torí naa, nigba ti a bá pada wo Mateu , ó sì sọ pé,

"Yoo wa rán awọn angẹli rẹ̀ pẹlu fere nla, wọn yoo

kó awọn ayanfẹ jọ," eyi ṣe deedee pẹlu ibi-kika yii, tí a bá ní kí a sọ ododo nipa pé

igbasoke awọn tí-a-gbàlà.

Oluṣọ-agutan Anderson: Kò ní nnkan kan ṣe pẹlu pe boya wọn jẹ́ Júù tabi Keferi kan, dudu ni

tabi funfun. Awọn ayanfẹ naa ni awọn tí a ti gbala, Yoo kó wọn jọ papọ nínú ìkùukùu

pẹlu rẹ̀. Njẹ eyi kì í ṣe deedee pẹlu ohun tí Tẹsalonika ori

sọ bí? Nigba ti ó sọ pe ìpè yoo dún, ati pe awọn tì a gbala ni yoo kó

kó jọ pẹlu Kristi. Nigba ti ò ṣe diẹ ní orí naa, ó sọ pé, "Sugbọn ní ti

ọjọ ati wakati naa. kó sí ẹnikan tí ó mọ́ ọ́..." tori bẹẹ, kò sí ẹni ti ó mọ̀ ọjọ tabi wakati naa tí eyi yoo ṣẹlẹ.

Emi kò le sọ fun ọ, "Yoo ṣẹlẹ ninu oṣu Kẹwaa, ní ọjọ bayii-bayii, ní ọdun yii " Lẹyin naa, ó tún sọ ní:

(Matthew :) Nigba naa ni ẹni meji yoo wà ni oko; a o mu ọ̀kan, a o si fi ekeji silẹ.

(Mateu :) Awọn obinrin meji yoo jumọ maa lọ ọlọ pọ̀; a o mu ọ̀kan, a o sì fi

ekeji silẹ.

(Mateu :) Nitori naa ẹ maa ṣọ́nà: nitori ẹyin kò mọ̀ wakati tí Oluwa yin yoo dé.

Oluṣọ-agutan Anderson: Tori bẹẹ ni Ọlọrun fi n sọ fun wa pe a kò mọ igba ti yoo jẹ́.

Ohun kan tí a gbọdọ maa sọ́nà fún ni. A kò mọ ọjọ tabi wakati naa, sugbọn o sọ fun wa pe LẸYIN

IPỌNJU NAA ni, nitori ó sọ pe LẸYIN IPỌNJU NAA ni òòrùn ati oṣupa yoo ṣókùnkùn,

nigba ti Jesu Kristi bá dé lawọsanma. Nigba yii ni fere máa dún. Nigba naa ni

a o gba awọn onigbagbọ soke. Titori pe a kò kàn mọ ọjọ tabi wakati naa, kọ́ ni yoo

duro fún pe kí a wá sọ pe o le ṣẹlẹ nigbakuugba. Ọpọlọpọ eniyan yoo wo pe,

"kò sí ẹni tí ó mọ̀ ọjọ tabi wakati naa," ti wọn yoo sì sọ pe "o le ṣẹlẹ nigbakuugba"

Ó dara, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pe LẸYIN IPỌNJU NAA ni. Eyi ni a maa rí nínú iwe

Mateu, Maaku, and Luuku. Mateu sọ nipa rẹ̀ ni ori , Maaku sọ tirẹ̀ ni ori ,

Luuku sọ tirẹ̀ naa ni ori ati ori , Lẹyin naa sì ni Johanu sọ tirẹ̀ ninu iwe Ifihan.

Awọn mẹrẹẹrin ni wọn sọ nipa rẹ̀. Akọkọ ni ipọnju naa, lẹyin eyi ni òòrùn ati oṣupa yoo ṣókùnkùn,

lẹyin naa ni Jesu yoo wá ninu ìkùukùu ni àkókò igbasoke naa.

Ìran - "Ipọnju" kò tumọ sí "ìbínú"

Oluṣọ-agutan Anderson: Idi tí awọn eniyan fi n rò pé igbasoke siwaju ipọnju naa ni

pe wọn n rò ó pé ipọnju naa tumọ sí ibinu Ọlọrun. Ọna kan lati fidi eyi mulẹ pe ibinu Ọlọrun

ati ipọnju naa yatọ si ara wọn patapata n bẹ ninu Mateu :, tí ó sọ pe,

Lojukan naa lẹyin ipọnju ọjọ wọnyii ni òòrùn yoo sokunkun, oṣupa

kì ì yoo sì fi imọlẹ rẹ̀ hàn." Tori naa, Bibeli hàn kedere ní Mateu pe òòrùn ati

oṣupa yoo ṣokunkun LẸYIN IPỌNJU NAA. Ó dara, bí o ba lọ sí iwe Ifihan ori nibi ti o ti maa kà

nipa àkókò naa ti òòrùn ati oṣupa tí ṣokunkun (nigba ti èdìdí kẹfa ṣí), ó sọ pe," ...

òòrùn sì dudu bi aṣọ onirun, oṣupa sì dabi ẹ̀jẹ̀; ọ̀kan naa gẹ́lẹ́ pẹlu

bí ó ti sọ ọ́ ni Mateu .

(Ìfihàn :) Awọn ìràwọ̀ oju ọ̀run sì ṣubu silẹ gẹgẹ bi ọ̀pọ̀tọ́ ti ṣe

n rẹ̀ àìgbó èṣo rẹ̀ dànù nigba tí ẹfuufu nla bá mì ín.

(Ìfihàn :) A sì ká ọ̀run kuro bí iwe ti a ká; ati

olukuluku oke ati erékùṣù ni a sì ṣí kuro ni ipo wọn.

(Ìfihàn :) Awọn ọba ayé ati awọn ọlọ́lá ati awọṅ olórí ológun,

ati awọn ọlọ́rọ́, ati awọn alagbara, ati olúkúlukú ominira si fi ara wọn pamọ́

ninu iho-ilẹ, ati ninu apata ori oke.

(Ìfihàn :) Wọn sì n wí fún awọṅ oke ati awọn apata naa pe, "Ẹ wólù wá, kí ẹ sì fi wa pamọ kuro

kuro loju ẹni ti ó jokoo lori ìtẹ́, ati kuro ninu ibinu Ọdọ-agutan naa:

(Ìfihàn :) Nitori ọjọ nla ibinu wọn dé; tani sì le duro?!

Oluṣọ-agutan Anderson: Tori naa, gẹgẹ bi eyi, nigba wo ni ibinu Ọlọrun nbẹ̀rẹ̀? Nigba ti

òòrùn ati oṣupa bá ṣókùnkùn ni ìgbà ti wọn sọ pe, "Ọjọ nla ibinu rẹ̀ ti dé."

Ọrọ-iṣe naa, TI dé, tumọ si pe ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ni. Tori naa, bí Mateu ba sọ pe òòrùn ati

oṣupa bá ṣókùnkùn LẸYIN IPỌNJU NAA, ati tí ibinu Ọlọrun kò bá bẹrẹ títí di ẹ̀yìn

ìgbà tí òòrùn ati oṣupa bá ṣókùnkùn, bawo ni wọn ṣe le jẹ nnkankan naa? Tori naa ibinu naa kò le bẹ̀rẹ̀

títí di ẹ̀yìn ìgbà tí òòrùn ati oṣupa bá ṣókùnkùn. Ní ọpọ igba, ti ẹ bá beere pe ki awọn eniyan

fi iwe-mimọ tí n sọ nipa igbasoke siwaju ipọnju hàn yin, wọn kò ní í rí ẹsẹ kankan fihàn yin. Mo maa pe

ẹnikẹni níjà pe kí ó fi ẹsẹ kan tó lo ọrọ naa "ipọnju" lati gbe

igbasoke siwaju ipọnju lẹ́sẹ̀. Wọn kò le ṣe é. Wọn maa ni lati fi awọn ẹsẹ tó lo

ọrọ bí i "ibinu" ni wọn maa fihàn yin. Wọn rí awọn ẹsẹ tí n ṣafihan pe awa Kristiẹni kò sí labẹ

ibinu Ọlọrun, wọn sì maa fi awọn ẹsẹ tí n sọ pe a kò kọ ibinu Ọlọrun mọ́ wa, ati pe,

a ti gba wá là lọwọ ibinu. Wọn sì sọ pe, "Wò ó, níbẹ̀, Bibeli sọ pe awa kò ní la

ipọnju kankan kọja. Sugbọn ẹ tilẹ duro ná: ipọnju ati ibinu kì í ṣe ọ̀kan naa rara!

Kò sí ẹsẹ kan nipa igbasoke n siwaju ipọnju tí o lo ọrọ naa "ipọnju" tí iru awọn onigbagbọ yii le fihàn yin

lati fi idi ẹkọ yii mulẹ. Awọn ẹsẹ kan ti n sọ nipa ibinu Ọlọrun ni wọn maa mu yin lọ.

Ibinu Ọlọrun ati ipọnju naa jẹ ohun meji tó yatọ patapata sí ara wọn. Ọpọ Kristiẹni ni wọn ti kọ́

wọn ninu ijọ wọn ati nipasẹ iwe tí wọn ti kà pé awọn ohun mejeeji yii jẹ́ ọ̀kan naa.

Ti o bá sì gbiyanju lati sọ fun wọn, "Gbọ́ mi! A maa wà nibi nígbà ipọnju naa! Igbasoke naa

kò ní í ṣẹlẹ titi di LẸYIN IPỌNJU NAA." Ohun ti wọn maa da ọ lóhùn niyi: "Rara o, Ọlọrun

kò ní í da ibinu rẹ̀ sori awọn eniyan rẹ̀ o. A kò kọ ibinu mọ́ wa. A maa

gbà wá lọwọ ibinu rẹ̀ ni. "Àní ẹ duro nà sẹ́: ṣe ọ̀kan naa ni ibinu ati ipọnju Ọlọrun ni?

Rara o. Tori naa, tí a bá lè fi òye ohun ti ọrọ naa, "ipọnju" tumọ sí yé awọn eniyan, wọn yoo

lóye pé LẸYIN IPỌNJU NAA naa yoo ṣẹlẹ siwaju igbasoke naa. Ó kàn jẹ́ pé awọn eniyan kò

lóye ọrọ naa, "ipọnju" tori pe wọn ní èrò kan ninu ori wọn pe ipọnju naa

jẹ́ àkókò ọlọ́dún meje kan nigba ti Ọlọrun yoo tú ibinu rẹ̀ síta, tí ó sì n da ina

ati òkúta-iná, tí ó n sọ omi di ẹ̀jẹ̀, tí ó sì n fi àkeekè dá awọn eniyan lóró, atí awọn

aburú loriṣiriṣị. Awọn yii kọ ni ipọnju naa o. Eyi kọ ni Bibeli kọni.

Ìran - Májẹ̀mu Tuntun Kọọkan Mẹ́nuba Ọrọ naa, "Ìpọ́njú"

Oluṣọ-agutan Anderson: Gbogbo awọn tí wọn gbagbọ ninu "igbasoke siwájú ipọnju naa" yii tabi igbasoke

tí yoo ṣẹlẹ siwaju ipọnju naa, tí ó le ṣẹlẹ nigbakuugba: ẹ jẹ́ kì a tu ìpèdè naa palẹ̀

"igbasoke siwájú ipọnju naa." Ó ní hóró mẹta ninu. "Siwájú" tumọ si kinni? "Kí ó tó sẹlẹ̀." Kinni

"ipọnju" dúró fún? "ìpọ́nnilójú." Lẹin naa ni a rí "igbasoke." Ọrọ naa "igbasoke" kò sí ninu

Bibeli. Àfijọ igbasoke n bẹ ninu Bibeli nitori pe a rí Jesu tí n bọ̀ wá

ní awọsanma, a sì gba awọn eniyan soke lati pade rẹ̀ lófurufú, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Torinaa, àfijọ

igbasoke wa nibẹ, sugbọn ọrọ naa gan an, "igbasoke" ní a kò lò nibẹ. Njẹ́ ọrọ naa, igbasoke n bẹ ninu

Bibeli bí? Tí ẹ ba wo ẹsẹ kọọkan tí a ti lo ọrọ naa, "igbasoke," ó hàn ni ẹẹmejilelogun

ninu Majẹmu Tuntun. Tori naa, tí Majẹmu Tuntun ba lo ọrọ naa ni ẹẹmejilelogun,

tí gbogbo eniyan sì tun lọ kiri pẹlu ẹkọ naa tí wọn n pe ní ̂igbasoke siwájú ipọnju naa," ṣé kò

yẹ kí ọ̀kan lara awọn ẹsẹ mejilelogun yii, tabi ibi-kika mejeejilelogun naa kọ wa ní ohun kan nipa igbasoke

kan ti yoo wáyé siwaju ipọnju naa bí? Ko si eyikeyi ninu ẹsẹ wọnyi tí ó sọ nipa igbasoke kan

tí yoo wáyé siwaju ipọnju naa tabi iru nnkan bẹẹ, tori naa, awọn eniyan oni-igbasoke siwaju ipọnju

naa ni lati gbáralé ọpọlọpọ àlàyé, wọn sì ní lati ṣàlàyé rẹ̀ fun yin, ó sì maa n saaba

ṣòro gan an. Mo ti ṣakiyesi ohun kan nipa Bibeli: Ọlọrun fẹ́ kí òye Bibeli yé wa

Kì í gbiyanju lati ṣe àrekérekè fun wa, kí ó da nnkan rú mọ́ wa loju tabi kí ó mú nnkan ṣòro fun wa.

Ó fẹ́ kí a mọ ododo. Ó nífẹ̀ẹ́ wa. Mo ti ṣakiyesi pe ni ọpọ igba, nigba akọkọ tí

Bibeli bá dá ọrọ kan silẹ, o maa n ṣe àlàyé rẹ̀ fun wa, ó sì maa n jẹ́ kí ó yé wa.

Ní ọna yii, tí a ba tun rí i ní ẹẹkeji, a maa mọ̀ ohun tí ó n sọrọ nipa rẹ̀. Bibeli

kà ní Mateu :

(Mateu :) Sugbọn kò ní gbongbo ninu ara rẹ̀, ó sì pẹ́ diẹ ni akoko kan; nigba ti wahala

tabi inúnibíni sì dide nitori ọrọ naa, lojukan naa oo sì kọsẹ̀.

Oluṣọ-agutan Anderson: Bawo ni ẹ ṣe ri àlàyé "ipọnjụ" sí. Inúnibíni ni. Ó sọ pe

"ipọnju" tabi "inúnibini"tí ó wáyé nitori ọrọ naa. Ṣe tori pe awọn eniyan yii búru gan an

ni wọn fi ń la ipọnju naa kọja ni bí? Bẹẹ kọ o, wọn ń la ipọnju kọja nitori wọn n duro deedee

ninu ọrọ Ọlọrun ni. Ati nitori pe wọn ti mú iduro wọn ninu ọrọ Ọlọrun ṣinṣịn,

nitori ti wọn ti fi ayọ gba ọrọ Ọlọrun, wọn yoo la inubini tabi

tabi ipọnju kọja. Tí a bà duro ṣinṣin tí a sì gbilẹ̀ ninu ohun tí a gbagbọ, nigba ti inunibini

bá dé, a maa faradà á. Igba akọkọ naa tí ẹ rí i tí wọn lo ọrọ yii "ipọnju" ninu Bibeli,

wọn lò ó ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹlu "inunibini" ni. Eyi ni igba akọkọ naa ti wọn lo ipọnju ninu

ninu Majẹmu Tuntun, ti ẹ ba sì n fi ọkàn bá igba kọọkan kaakiri inu Majẹmu Tuntun tí

wọn lo ọrọ naa "ipọnju" lọ, igba mẹsan an ninu mẹwaa ní n tọka sí pe awọn onigbagbọ n la ipọnju

kọja - ànì ìrírí naa tí awọn ẹni-igbala là kọja. Awọn igba meji yooku ti wọn tun lò ó nibi tí

wọn kò ti lò ó nipa awọn ẹni-igbala, kò ní í nnkankan ṣe pẹlu asọtẹlẹ nipa igba ikẹyin. Ó kàn

n sọrọ nipa awọn eniyan ti wọn n la ipọnju kọja lapapọ ni. Kaakiri itan ayé ni awọn Kristiẹni

ti la ipọnju kọja, tí kò sì ní í yatọ ní ìran tiwa yii pẹlu. Boya eyi naa maa

ṣẹlẹ ni igba ayé tiwa, boya bẹẹ kọ, sugbọn tí ó bá ṣẹlẹ ni igba ayé tiwa, a maa là á

kọja bí onigbagbọ ni. Ninu kí wọn ṣe iku pa wá nitori ọrọ Kristi, tabi ó ṣeéṣe kí

a là á igba yii kọja títí tí igbasoke naa yoo ṣẹlẹ.

Oluṣọ-agutan Jimenez: Ìgbà ẹkarun un tí ọrọ naa "ipọnju" tún jẹyọ ninu Majẹmu Tuntun ní a rí ní

in Johanu :.

Oluṣọ-agutan Anderson: Ó n bá awọn onigbagbọ sọrọ. Awọn ọmọ-lẹyin rẹ̀ ni ó n ba sọrọ. Ó sọ pe

(Johanu :) Mo ti sọ nnkan wọnyii fun yin kí ẹ le ní alaafia nipa wíwà ninu mi. Ẹ óo

ní ipọnju ninu ayé, sugbọn ẹ ṣe ara gírí, mo ti ṣẹgun ayé!

Oluṣọ-agutan Anderson: Njẹ ó sọ pe iwọ yoo wà láìní ipọnju bi? Njẹ ó sọ

pe iwọ kò ní í la ipọnju kọja bi? Njẹ ó sọ pe, "Emi kò ní í jẹ kí awọn eniyan mi la ipọnju kọja!

Mo nifẹẹ wọn pupọ!" Rara o! Kinni igba akọkọ ti a kọ nipa "ipọnju" sọ ní Mateu ?

Pe tí awọn eniyan kò bá duro ṣinṣin kí wọn sì gbilẹ̀, tí inunibini tabi ipọnju bá dide

nitori ọrọ naa, igbagbọ wọn le yẹ̀. Ẹ wo nnkan ti Jesu sọ ni ori ibi-kika naa

tí ó kilọ fun wa ni ẹsẹ ekini:

(Johanu :) Mo sọ gbogbo nnkan yii fun yin kí igbagbọ yin ma ba à yẹ̀

Oluṣọ-agutan Anderson: Ó n sọ pe tí oun kò ba sọ fun yin nipa eyi, ti oun kò bá kilọ fun

yin nipa awọn inunibini ati ipọnju ati idanwo ti ẹ maa là kọja ninu

ayé yin, tí wọn bá ṣẹlẹ, yoo ba yin lójijì. Ẹ maa sọ igbagbọ yin nù. Ẹ le sọ pe, "Kilode

tí ẹ n waasu iru eyi, Oluṣọ-agutan Anderson?" Mo n ṣe iwaasu yii kí

igbagbọ yin má ba à yẹ̀. Ẹ sọ pe, "Duro ná, iwaasu yii n bi eniyan ninu jare!" Rara o, iwaasu yii n wá

kí igbagbọ rẹ má ba à yẹ̀ ni o, tori Jesu sọ pe tí ẹ ba mọ̀ pé eyi n bọ̀, igbagbọ

yin kò ní í yẹ̀. Wo ẹsẹ kẹrin:

(Johanu :) Sugbọn mo ti sọ gbogbo nnkan wọnyi fun yin, kí ẹ le ranti pe

mo ti sọ fun yin tẹlẹ, nigba ti ó bá yá, tí wọn bá n ṣe é si yin. N kò sọ awọn nnkan wọnyi fun yin lati

ibẹrẹ nitori mo wà lọ́dọ̀ yin.

Oluṣọ-agutan Anderson: Ó sọ ọ́ nibẹ pe nigba ti awọn nnkan yii ba ṣẹlẹ, ẹ maa ranti pe

mo sọ bẹẹ fun yin, mo sì n sọ ohun kan naa tí Jesu sọ naa lalẹ yii. Nigba ti nnkan wọnyi

bá bẹrẹ sí ní í ṣẹlẹ - o le mà jẹ́ ní sáà tiwa yii; o le jẹ́ ọgọrun un ọdun sí ìsìnyii; boya o tilẹ

le jẹ́ ọdun diẹ sí akoko yii; a kò mọ igba tí igbẹyin maa dé - sugbọn nigba ti ó ṣẹlẹ,

ẹ maa ranti pe mo sọ fun yin. Ni pataki ju eyi lọ, nitori pe kì í ṣe lati ọgbọn ori mi

ẹ maa ranti pe Jesu sọ bẹẹ fun yin.

Oluṣọ-agutan Jimenez: Igba miran tí ẹ tún le gbọ ọrọ naa, "ipọnju" ni a rí ninu Ìṣe Aposteli :, ó

sọ pe,

(Acts :) Wọn n mú awọn onigbagbọ lọ́kàn le, pe kí wọn duro ṣinṣin ninu igbagbọ.

ọn n fi yé wọn pé kí eniyan tó wọ ijọba Ọlọrun, ó ni lati ní ọpọlọpọ ìṣòro.

Oluṣọ-agutan Jimenez: Gbolohun tí ó fanimọra yii n sọ pe "a ni lati la iṣoro pupọ kọja

kí a tó le wọ ijọba Ọlọrun" - gbolohun kan yii lati inu Bibeli pe

awa yoo ni lati la ipọnju kọja fun wa nigba ti a bá maa wọ ijọba Ọlọrun, kì í ṣe pe

a maa wọ ijọba Ọlọrun siwaju ipọnju.

Oluṣọ-agutan Anderson: Njẹ ó sọ pe, Eniyan yoo wà laaye, yoo dara pe awa yoo ti lọ siwaju ipọnju naa!"

Rara o, ó sọ pe, "Ó dara ju kí a ní idaniloju nipa wọn. Ó dara ju kí a mú wọn duro ṣinṣin nipa awọn nkankan.

Ó dara pupọ kí a dì wọn lámùrè nitori pe ó sàn kí wọn mọ̀ pe nipasẹ ọpọ ipọnju

ni wọn maa wọ ijọba Ọlọrun." Njẹ nọmba kẹfa sọ nipa igbasoke kan ti n siwaju ipọnju bi?

Emi kò rò bẹẹ.

Oluṣọ-agutan Jimenez: Ní Kọrinti :, Bibeli sọ pe:

( Kọrinti :) Ọkàn mi balẹ̀ lori ọrọ yin. Mo n fi ọwọ yin sọ̀yà, mo ti ní ìtùnú kíkún

ninu gbogbo ipọnju wa, mo ní ayọ lọpọlọpọ.

Oluṣọ-agutan Anderson: Kò sọ pe, ayọ mi kún pupọ nitori emi kò ní la ipọnju kọja.

Ayọ mi pọ̀ pupọ pe a maa gba wa soke siwaju ipọnju naa!" Ohun tí ó sọ kọ niyi.

Ó sọ pe, "Ninu gbogbo ipọnju wa, mo ni ayọ lọpọlọpọ." Nibo ni igbasoke siwaju

ninu ibi-kika yii? Kò sí nibẹ.

Oluṣọ-agutan Jimenez: Ó jẹ́ iyalẹnu fun mi pe bí ẹ ṣe n fojúrí ọrọ naa, "ipọnju" kaakiri inu

iwe-mimọ, ẹ maa rí atọka nílọ̀póo-nílọ̀póo sí awọn onigbagbọ tí n sọ pe wọn n la

ipọnju kọja. Ó sọ pe, "...ninu gbogbo ipọnju wa." Kì í ṣe ohun ti oní-gbàgbọ́ kò ní í là kọja.

Ohun tí onígbàgbọ́ tí n là kọjá fún gbogbo ọjọ aye wọn ni.

Lati ìrandíran, ni awa onigbagbọ ti la ipọnju kọja.

Oluṣọ-agutan Anderson: Ẹ fi sọ́kàn o, ẹyin ara, Ọlọrun kò lè fi júrujùru bò wá loju. Kò gbiyanju lati

dà wá báṣabàṣa. Eniyan ni ó ti n ṣe yin báṣabàṣa! Awọn oniwaasu ni wọn ti n ṣe yin báṣabàṣa!

Eré ori móhùmáwòrán ati awọn fíìmù (Awọn Tó Kù Lẹ́yìn, abbl.) ni n ṣe yin báṣabàṣa!. Ọlọrun kò lè ṣe

yin báṣabàṣa!

Oluṣọ-agutan Jimenez: Tí a ba gba Bibeli laaye kí ó ṣiṣẹ atúmọ̀, tí a sì gba Bibeli laaye

lati ṣàlàyé awọn ọrọ fun wa, a wa yoo rí i pe ọrọ naa, "ipọnju" kì í ṣe ni ibinu Ọlọrun.

Inúnibíni ni, ìnira ni. Wahala ni.

Oluṣọ-agutan Anderson: Ẹ maa rò pe ẹṅikan le fi ọ̀kan lara awọṅ ẹsẹ mejilelogun naa hàn yin.

Ẹ fi ẹsẹ kan hàn mi tó sọ pe a ti maa lọ kí ipọnju naa tó ṣẹlẹ, tabi pe a maa

pàdé lókè siwaju ipọnju naa, tabi pe igbasoke yoo ṣẹlẹ siwaju ipọnju naa.

Sibẹ mo le fihàn yin ní daju-ṣáká awọn ibi naa ti Bibeli ti sọ pe lẹsẹkẹsẹ lẹyin ipọnju naa,

Jesu m bọ lawọsanma, fèrè yoo dún, tí awọn ayanfẹ yoo sì pade pẹlu

lókè ninu ìkùukùu. Kò jù bẹẹ lọ. Awọn tí wọn gbagbọ ninu igbasoke siwaju ipọnju naa

ní lati gbarale awọn eniyan naa tí wọn n ṣe gbédègbẹyọ̀ ati ọgbọn-ori, ati pe,

"Kò buru naa, nigba tó jẹ pe a kò kúkú mọ ọjọ tabi wakati naa, ó jásí pe igbakuugba ni ó ṣẹlẹ,

tí ó bá sì le ṣẹlẹ nigbakuugba, a jẹ pe siwaju ipọnju naa ni yoo jẹ." Tabi wọn yoo

ní awọn aworan tó ṣoro lati mọ̀ fun yin. Sugbọn tí ẹ ba kàn gbe Bibeli yin, ti ẹ sì

ní gẹ́lẹ́ bí ẹ ṣe rí i ninu rẹ̀ - ki ẹ ka Majẹmu Tuntun bẹrẹ lati Mateu ori ekini, - tí ẹ bá ti dé Mateu

ori , ibẹ ló wà, tó mọ́ gaara bí oju-ọjọ: LẸYIN IPỌNJU NAA Jesu n bọ̀ lawọsanma.

Ìran - Ọ̀mọ̀wé Kent Hovind ni yii

Oluṣọ-agutan Anderson: Ọ̀mọ̀wé Kent Hovind jẹ gbajumọ ajiyinrere tí ó gbagbọ ninu igbasoke siwaju ipọnju naa

tí ó sì tun nwaasu nipa rẹ̀ fun ọdun mejidinlogun. Sugbọn ni bayii, ó wa lẹ́wọ̀n, lati igba tí ó sì ti

wà lẹ́wọ̀n naa, óti n ka Bibeli rẹ̀, ó sì wá han gba-n-gba sí i pe igbasoke n siwaju ipọnju naa

kò sí ninu iwe-mimọ, mo sì fẹ pe e sori ago bayii lati mọ sí i nipa ohun tí ó mú u

yipada ninu èrò rẹ̀. Ki lo mú u sọjí pe LẸYIN IPỌNJU NAA ni?

Ọmọwe Kent Hovind: Orukọ mi ni Kent Hovind. Mo jẹ olukọ imọ sayẹnsi ni girama fun ọdun mẹẹdogun

lẹyin naa ni mo di ajiyinrere fun ogun ọdun, ti mo n kọni nípa ìṣẹ̀dá ati ìyírapadà. Mo sì ti

n kọminu lori ojuwoye mi nipa igba ikẹyin ati bí ó ṣe tan mọra wọn ninu iwe-mimọ,

mo sì ti rí àrídájú bayii, eyi ṣẹlẹ ní bí ọdun mẹta sẹyin, pe ohun tí wọn fi gbogbo aye mi kọ mi

kì ì ṣe otitọ. Mo ni lati yi ọkàn mi pada, sí àìdunnú awọn ara-mi-ninu-Oluwa,

nitori iduro mi bayii tako igbasoke siwaju ipọnju naa. Bibeli sọ pe ní ikẹyin ọjọ, awọn

awon ẹlẹgan yoo fínnúfíndọ̀ kọ eti ikún sí ìṣẹ̀dà, ìkún-omi, ati idajọ ti n bọ. Kò burú, Mo lo

ogun fi kọ awọn eniyan kaakiri agbaye nipa iṣẹda ati ikun-omi, sugbọn mo mọ̀ọ́mọ̀

má kọbi-ara sí kikọni ni idajọ ti n bọ̀, nitori idi kan pe, kò fi bẹẹ ye emi gan an funra mi. Ní

Mateu ori , ni a ti rí iwaasu Jesu nibi ti awọn ọmọ-lẹyin rẹ̀ ti beere lọwọ rẹ̀ kedere pe: kinni

awọn àmì pipadabọ rẹ? Ati pe nigba wo ni yoo ṣẹlẹ? A rí itan yii kan naa kà ninu Maaku

ori ati ni Luuku , tori naa mo da awọn oju-iwe Bibeli lati ibi-kika mẹtẹẹta naa kọ, mo sì gbé wọn

ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ ànì awọn akọsilẹ mẹtẹẹta yii. Lọgan tí ó bá ti yọ gbogbo awọn

àlàyé inu rẹ̀ jade tan, yoo sì bẹrẹ sí ní mọlẹ gaara sí i pe ọrọ lori igbasoke siwàjù ipọnju

kì í ṣe otitọ.

Oluṣọ-agutan Anderson: Kinni idi ti ẹ fi rò pe ọpọ gbagbọ ninu igbasoke siwájú ipọnju naa? Ki lode

tí ẹkọ yii ṣe gbajumọ tó bẹẹ?

Ọ̀mọ̀wé Kent Hovind: Nitori pe ó bá wọn dahun awọn ibeere adójútini kan. Onigbagbọ kò le dahun

awọn ibeere nipa ẹranko dáínósọ̀ọ̀. Nibo ni wọn bámu? Nitori naa ni wọn ṣe ronu "kinni kí a sọ"

tí wọn sì gbà á bẹẹ. Mo lérò pe ọrọ lori igbasoke siwájú ipọnju naa ṣe wẹ́kú pẹlu

ìsọ̀rí awọn eniyan elétí ikún ni. Ohun ti ó n wùwọn gbọ ni yii.

Oluṣọ-agutan Anderson: Bẹẹ ni o.

-

-

Ọmọwe Kent Hovind: Wọn fẹ gbọ, " Wò ó, Emi kò nílò lati farada ijiya." Ò dara, Jesu

sọ pe asiko ipọnju kan n bọ̀, iru eyi tí oju kò rí iru rẹ̀ rí lati igba tí ayé ti bẹrẹ. Ànì,

ṣe iwọ rò pe Ìfipágbọ́tẹnu-ẹni awọn Spaniṣi búru? tabi Ìpaláparun awọn Júù lati ọwọ awọn Jamani

jàì? Tabi ti Ìṣenúnibíni Awọn Romu sí awọn Kristiẹni? Yoo buru ju gbogbo awọn yii

lapapọ lọ.

Oluṣọ-agutan Anderson: Ó ga o. Eyi lé kenkà o.

-

-

Ọmọwe Kent Hovind: Ayé bẹrẹ pẹlu pe Kaini pa Abẹli - awọn eniyan buburu n pa

awọn eniyan rere.

Oluṣọ-agutan Anderson: Otitọ ni.

Ọmọwe Kent Hovind: Bí ó ṣe rí niyi lati ìgbà tí aláyé ti dáyé. Jesu sì sọ fun wọn pe nigba ti

wọn ba pa yin tabi tí wọn ṣe inunibini sí yin, ẹ yọ̀, nitori èrè yin tobi

ijọba ọrun.

Oluṣọ-agutan Anderson: Tí a bá mú itumọ Bibeli fun ohun ti "ipọnju" tumọ sí (tí kì í ṣe

itumọ ìdibàjẹ̀ tí wọn fun) - tí a bá mú itumọ inu Bibeli fun

"ipọnju," gan an, ṣe ẹ kò ní sọ pe ẹ n la ipọnju kọja bayii bí?

Ọmọwe Kent Hovind: Bẹẹ ni o. "Ipọnju" ni awọn ohun naa tí ayé n ṣe sí wa, ó sì ti

ṣẹlẹ fun ẹgbẹgbẹrun ọdun. Jesu sọ pe, "Ninu ayé yii ẹ oo rí ipọnju: sugbọn

ẹ tújúká: tori ti mo ti bori ayé." Kristiẹni ni lati reti ipọnju o, èrè

sì n bẹ fun wa tí a bá là á kọja pẹlu ifarada.

Ìran - Àlàkalẹ̀-àkókò ninu Ìwé Ìfihàn

Oluṣọ-agutan Anderson: Ọmọwe, ni bayii, nigba ti ó ti jẹ́ pe isọri jẹ́ ti "Alákatakítí Ẹ̀sìn" eyi le bọ

sí isọri kan ni ọkàn awọn eniyan kan, lati maa ró pe igbẹyin maa dé sí

ayé yii - pe ipadabọ ẹlẹkeji Jesu Kristi yoo ṣẹlẹ gẹlẹ. Idi niyi tí

mo kàn fẹ ṣàlàyé fun yin ní kukuru - mo kàn fẹ fun yin ní àlàkalẹ́-àkókò lérèfé

lori awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ gẹgẹ bi Bibeli ṣe sọ, ati bí wọn yoo ṣe ṣẹlẹ.

Oluṣọ-agutan Anderson: Mo lérò pé kọ́kọ́rọ́ sí ìlóye Ìwé Ìfihàn ni lílóye bí

ó ti nṣẹlẹ̀. Ọlọ́run fún wa ní Ìwé Ìfihàn láti sá wà ní bẹẹ gẹlẹ - ìfihàn kan - láti ṣe àfihàn

àwọn nnkan yìí fún wa, láti máṣe fi wọ́n pamọ́. Kì í ṣe ìwé Ìfarasin. Ó jẹ́ ìwé

ti Ìfihàn, Ọlọ́run sì nfẹ́ kí ó yéni pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Ìdí nìyi tí ó fi fún wa ní

ọ̀nà tí ó fi lè tètè yéni. Tí ẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí íkà á ní orí ìkíní, ẹ wà

ní sáà ti Kristi àbí agbègbè ibẹ̀ nítorí pé Johannu wà ní erékùsù Patimo, tí Johannu sì ti

nrí inúnibíni fún kíkéde Ìhìnrere, nítorí náà a nsọ nípa sáà tí ó dín ní ọgọ́rùn ún ọdún

lẹ́yìn wíwá Kristi sí ayé yìí. Nígbà náà ni ó nrí ìran níbi tí ó ti nrí Jesu

Kristi Olúwa tí ó nfi ara hàn án. Lẹ́yìn náà ní orí ìkejì sí ìkẹta Jesu Kristi nránṣẹ́

sí àwọn ìjọ méje ti Asia yìí, tí ó sì hàn pé àwọn yii ni ìjọ ti àkọ́kọ́

ní sáà ọgọ́rùn ún ọdún, ní àkókò naa. Lẹ́yìn náà ní orí ìkẹrin sí ìkarùn ún, a rí ìran náà lókè ọ̀run níbi tí ó

júwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó nṣẹlẹ̀ ní Ọ̀run. Lẹ́yìn náà ní orí kẹfà a dé ibi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí

ìpọ́njú náà gan an. Orí keje ni ibi tí ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ti nfarahàn ní Ọ̀run - tí ó hàn pé òun ni

ìgbàsókè náà - gbogbo orílẹ̀-aye àti èdè ni ó péjú níbẹ̀. Lẹ́yìn náà ní ẹsẹ ìkẹjọ sí ìkẹsàn án, ẹyin

yoo rí Ọlọ́run tí ó nrọ̀jò ìbínú rẹ̀ lórí ayé yìí. Lẹ́yìn náà ní orí ìkẹwàá jẹ́ orí ìwé tí ó lápẹẹrẹ

tí ó nsọ nípa àwọn nnkan díẹ̀ kí ipè keje tó dún. Lẹ́yìn náà ní orí ìkọkànlá a rí

ipè keje tí ó ndún. Gbogbo ìyẹn láti sọ èyí: tí ẹ bá wò ìwé Ìfihàn,

àwọn orí mọ́kànlá àkọ́kọ́ ntẹ̀lé àlàkalẹ̀ àkókò tí ó mọ́gbọ́n dání. Ẹ nbẹ̀rẹ̀ ní nnkan bí

sáà Kristi, tí ó pẹ́ tó Kristi. Lẹ́yìn náà ẹ ó wọnú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ fun

ọjọ́ iwájú: ti i se ìpọ́njú náà, lẹ́yìn náà ni ìgbàsókè, lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run nrọ́jò ìbínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà nígbà tí

ipè ìkeje bá ndún ní orí ìkọkànlá, ìbẹ̀ ni òpin wà, níbi tí ó ti nsọ pé, Ìjọba

ayé di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀; on o si jọba

lai ati lailai. Ṣùgbọ́n ohun tí ó dùn mọ́ni ni pé tí ẹ bá dé òpin orí

ìkọkànlá, ẹ rí òpin naa ní ìkẹyìn. Ó dára, lẹ́yìn náà ẹ ó dé orí ìkejìlá, ìbẹ̀ sì ní

a ti ri ayipada nlá ninu iwe Ifihan nitori pe ti a bá wo ẹsẹ ikinni ti ori ikejilá tí

a ṣẹ̀ṣẹ̀ wò. O nsọ pé:

Àmi nla kan si hàn li ọrun;obinrin kan ti a fi

õrun wọ̀ li aṣo, oṣupa si mbẹ labẹ ẹsẹ rẹ̀, ade onirawọ mejila si mbẹ ni ori rẹ̀:

(Ifihan :) O si lóyun, o si kigbe ni irọbi, o si wà ni irora

ati bimọ.

(Ifihan :) Àmi miran si hàn li ọrun; si kiyesi i, dragoni pupa nla kan,

tí ó ní ori meje ati iwo mẹwa ati adé meje li ori rẹ̀.

(Ifihan :) Ìru rẹ̀ si wọ́ idamẹta awọn irawọ, o sì ju

wọn si ilẹ aiye, dragoni naa si duro niwaju obinrin na ti o fẹ bímọ,

pe nigbati o ba bí, ki o le pa ọmọ rẹ̀ jẹ.

Oluṣọ-agutan Anderson: Ẹ wa fiyesi ẹsẹ ikarun un daradara:

(Ifihan :) O si bí ọmọkunrin kan ti yio fi ọpá irin

ṣe akoso gbogbo awọn orilẹ-ède: a si gbà ọmọ rẹ̀ lọ soke si ọdọ Ọlọrun, ati si ori itẹ́ rẹ̀.

Oluṣọ-agutan Anderson: O hàn bayii pe ọmọ yii ni Jesu Kristi nitori pé ninu Majẹ̀mú Laelae

ati Májẹ̀mú Tuntun, Bibeli nsọ nipa Jesu Kristi ti ó nfi ọpá irin ṣe akoso aye yii

ti ó sì ntọka si ijọba ẹgbẹrun ọdun ti o mbọ lọjọ iwaju. Nitori naa, nitootọ

ọna ti o dara julọ ti mo fi lè ràn yin lọwọ lati lóye iwe Ifihan ni pe ki nsọ fun yin lati ké e

sí meji ni ori ikọkanla gan an. Ẹsẹ ikinni si ikọkanla jẹ abala kan tí ẹsẹ ikejilá sí ikejilelogun sì jẹ́ abala miran. Lẹyin naa, tí

ẹ bá fi abala wọnyi wé ara wọn, ẹ ó rí awọn iṣẹlẹ kan naa lati oju-ìwò meji ti o yatọ:

Ikinni Ọdun kejila ti inú Ọgọrun un ọdun akọkọ

Ikeji

Ikẹta

Ikẹrin

Ikarun un

Ikẹfa Ipọnju Ikẹtala

Ikeje Igbasoke Ikẹrinla

Ikẹẹdogun

Ikẹjọ Ibinu Ọlọrun Ikẹrindinlogun

Ikẹsan an

Ikẹwaa

Ikọkanla

Babiloni Ikẹtadinlogun

Ikejdinlogun

Amagẹddoni Ikọkandinlogun

Ìtẹ Funfun Ogún

Ọ̀run/Ayé Tuntun Ikọkanlelogun

Ikejilelogun

Oluṣọ-agutan Anderson: Ki lo dé ti Ọlọrun yoo fi ṣe bẹẹ? Ki lo de ti Ọlọrun yoo fi sọ itàn kan naa nigba meji ninu

iwe Ifihan? O dara, ki lo de ti ó fi sọ itàn Ihinrere fun wa nigbà mẹrin ninu Mateu,

Maaku, Luuku, ati Johannu? Ki lo de ti ó fun wa ni iwe Samuẹli Kinni ati Ikeji ati Awọn Ọba Kinni ati Ikeji, ṣugbọn

lẹyin naa ni ó tun fun wa ni Kronika Kinni ati Ikeji lati fun wa lati igun miran, ìwòye miran, a sì

lè kẹ́kọọ pupọ nipa ṣiṣe afiwe iwe Àwọn Ọba pẹlu iwe Kronika,

àbi ṣiṣe afiwe iwe Mateu pẹlu Maaku, ati Maaku pẹlu Luuku, ati Luuku pẹlu Johannu, awọn yii sì nfun wa ni

ìwòye ọtọọtọ. O dara ọna kannaa tí a fi mòye iwe Ifihan niyi.

Eyi yoo ràn ìmòye yín nípa iwe Ifihan lọwọ nigba ti ẹ bá lóye bí ó ti tẹ̀lé ara wọn bẹẹ.

Awọn kan wá lérò pé iwe Ifihan kò wà ni ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé rara, ṣugbọn àkànlò ede

"lẹyin eyi" abi àkànlò ede "lẹyin nnkan wọnyii" waye nígbà mẹwaa ninu iwe Ifihan.

Tí a ba nrí "lẹyin eyi" ati "lẹyin nnkan wọnyii" tí ó nfarahan leralera, eyi jasi pe Ọlọrun nfun wa

ní alakalẹ bi awọn iṣẹlẹ ti tẹle ara wọn.

Oluṣọ-agutan Jimenez: Ó jẹ́ nnkan ti o buni kù lati gbiyanju lati tumọ Bibeli abi kà Bibeli

lati takò otitọ pé Bibeli nsọ pé "lẹyin eyi," tí awọn eniyan sì nsọ pe, "Kò si ní

ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ko mọ́gbọ́n wá." Jakejado Bibeli, bí ẹ ó ti ka iwe mimọ́ niyẹn.

Apẹrẹ kan ti o pani lẹ́rín: ninu Johannu, ori kẹta, ẹsẹ ikọkanlelogun, o nsọ pé:

(Johannu :) Ṣugbọn ẹniti o ba nṣe otitọ ni iwá sí imọlẹ, ki iṣẹ rẹ̀ ki o le fi ara hàn pe,

a ṣe wọn nipa ti Ọlọrun.

Oluṣọ-agutan Jimenez: Lẹyin naa ni ẹsẹ ikejilelogun nsọ pe, "Lẹhin nkan wọnyi Jesu pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá

si ilẹ Judea;" yoo si buni kù fun mi lati duro nihin ki nsì sọ pe, "Bẹẹkọ,

dajudaju, ẹsẹ ikejilelogun waye ṣaaju ẹsẹ ikọkanlelogun," nigba tí ẹsẹ ikejilelogun nsọ pe "lẹhin nkan wọnyi."

A ó bojuwo eyi ti a ó sì wipe, nitootọ, bi a ti kọ ọ́ niyẹn, iyẹn si ni ohun

tí ó tumọ sí. Lẹyin naa ni a de inu iwe ịfihan, gẹgẹ bi mo sì ti sọ, igba mẹwaa ni ẹ ó ka "lẹhin

nkan wọnyi" tabi "lẹhin eyi," sibẹ awọn eniyan nsọ pe, "Bẹẹkọ, kò tẹle ara wọn.

Kò mọ́gbọ́n wá." Ó jẹ́ ọna ti ó lòdì lati ka Bibeli.

Oluṣọ-agutan Anderson: Eyi jasi pe, tí ẹ ba ni ero pe ó wà ni ṣíṣè-n-tẹ̀lé, ṣugbọn ó tun pada bẹrẹ lẹẹkan sí i

ni ori ikejila, eyi yoo jẹ ki ó ye yin. Mo fẹ́ là ori iwe meji pere kọja

nihin lati fihàn yin bi awọn iṣẹlẹ igba ikẹyin ti tẹle ara wọn. Eyi lè waye ni ọgọrun un ọdun sí

akoko yii. Gbogbo wa lè ti papòdà, ṣugbọn mo lero pe ó ṣeeṣe ki ó ṣẹlẹ

laipẹ ọjọ. Ni tootọ, yoo ṣẹ̀rù ba mi tí ó ba jẹ pe o kéré tan awọn nnkan yii ko ṣẹlẹ ní

oju ẹmi mi ti ó ba jẹ́ pe mo lò akoko ti ó yẹ kí nlo. mo jẹ ọmọ ọdun mọkanlelọgbọn, bi nnkan si ti

nsare ni lọọlọọ yii, yoo jẹ iyalẹnu fun mi tí eyi ko ba ṣẹlẹ ni ogoji ọdun sihin yii.

Nigba ti mo bá bẹrẹ sí í wọnu iṣẹ́-iranṣẹ ti aṣalẹ yii, mo lero pé ẹ ó lóye diẹ ninu idi ti

mo fi sọ bẹẹ. Ohun ti o nbẹrẹ ipọnju naa niyi. Bibeli wi pe Eṣu,

abi Satani, ni a ó lé kuro ni Ọrun. Ẹ wá nsọ pé, "Duro ná, Oluṣọ-agutan Anderson,

ṣe iyẹn ko ti ṣẹlẹ tẹlẹ?" Ṣugbọn idahun naa ni, Rara o. Awọn eniyan ro pe Eṣu wa ni Ọrun Apaadi

ni lọwọlọwọ yii, ṣugbọn n itootọ, Eṣu ko ti i dé Ọrun Apaadi rí nitori pe Bibeli nfi

yé wa pe Eṣu wa lori ilẹ aye yii ti ó nrin kiri gẹgẹ bi kiniun ti ó nbú ramu-ramu ti ó nwa ẹni ti

yoo pajẹ kiri. Eṣu ati gbogbo awọn ẹmi aimọ́ rẹ̀ wà lori ilẹ aye yii ninu Bibeli.

Ó nrin soke sodo laarin Aye ati Ọrun, ó si n bá Ọlọrun sọrọ. Ti ẹ ba ka iwe

Jobu, Eṣu nwá ti ó si nduro niwaju Ọlọrun ti ó si ni ìtàkurọ̀sọ pẹlu Ọlọrun ní Ọrun

nipa Jobu iranṣẹ rẹ̀. Nitornaa Eṣu nlọ soke sodo nisisiyi. Ó dara, Bibeli nsọ

nipa ọjọ kan ti a ó lé Eṣu sọkalẹ lati Ọrun:

(Ifihan :) Ogun si mbẹ li ọrun: Mikaeli ati awọn angẹli rẹ̀ ba dragoni na

jagun; dragoni si jagun ati awọn angẹli rẹ̀.

(Ifihan :) Nwọn kò si le ṣẹgun; bẹ̃ni a kò si ri ipo wọn mọ́ li ọrun.

(Ifihan :) A si lé dragoni nla na jade, ejò lailai nì, ti a npè ni Èṣu,

ati Satani, ti ntàn gbogbo aiye jẹ, a si lé e jù si ilẹ aiye, a si le awọn angẹli rẹ̀

jade pẹlu rẹ̀.

(Ifihan :) Mo si gbọ́ ohùn rara li ọrun, nwipe, Nigbayi ni igbala de, ati

agbara, ati ijọba Ọlọrun wa, ati ọla ti Kristi rẹ̀; nitori a ti lé olufisùn awon

arakunrin wa jade, ti o nfi wọn sùn niwaju Ọlorun wa lọsàn ati loru.

(Ifihan :) Nwọn si ṣẹgun rẹ̀ nitori ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na, ati nitori ọ̀rọ

ẹrí wọn, nwọn kò si fẹran ẹmi wọn ani titi de iku.

(Ifihan :) Nitorina ẹ mã yọ̀, ẹnyin ọrun, ati ẹnyin ti ngbé inu wọn. Egbé ni fun

aiye ati fun nitori okun! nitori Eṣù sọkalẹ tọ̀ nyin wá ni ibinu nla,

nitori o mọ̀ pe ìgba kukuru sá li on ni.

Oluṣọ-agutan Anderson: Nitori naa, kini a nrí nihin? Ogun wà ni Ọrun, Bibeli sì nkọni

pé Eṣu npadanu ogun yii. Ó npadanu ogun yii ni Ọrun, nitori pe o si padanu

ogun naa, oun ati awọn angẹli rẹ̀, ti ó nfihan nihin pé ó jẹ́ idamẹta awọn angẹli, a

lé wọn sí aye. Satani gan an ni a lé kuro ni ọrun yii, oun si mọ̀

akoko kukuru kúkú ni oun ní, oun yoo si jade lọ lati pọ́n awọn onigbagbọ loju ki ó si pọ́n

awọn eniyan mimọ loju ki ó si gbiyanju lati pa wọn run. Ẹ wo orí ikẹtala. Nibi yii ni ogun naa ti nbẹrẹ.

Ní Ifihan :, oun yoo jagun. Bawo ni yoo ti ṣe é? Bawo ni Eṣu yoo ti

bá awọn onigbagbọ jagun?

Ìran : Asòdì-sí-Kristi

Oluṣọ-agutan Anderson: Ohun ti ó kàn ti a ó rí ti yoo ṣẹlẹ ninu isọtẹlẹ ni ohun ti a npè ni

ipọnju naa. Ipọnju naa ni akoko tí ọpọlọpọ iṣẹlẹ nṣẹlẹ

lori ilẹ aye yii ti ó buru. Ìyàn yoo wà. Ajakalẹ arun yoo wà.

Ogun-jija yoo wà - ọpọlọpọ ogun-jija. Ebi yoo maa pa ọpọlọpọ

eniyan kú, ti aisan yoo si maa pa wọn. Ọpọlọpọ ohun buburu ni yoo maa ṣẹlẹ. Ó dara, ninu gbogbo

ogun-jija yii ati ajalu ti yoo maa ṣẹlẹ nigba ipọnju naa, (kì í ṣe ajalu

ti ó ti ọwọ́ Ọlọrun wa, kì í ṣe pé Ọlọrun nrọjo iná ati imí-ọjọ́ ṣugbọn dipò bẹẹ awọn ajalu ti iṣẹda, ogun-jija, ìyàn,

tí awọn eniyan nfà) ẹnikan yoo wà ti yoo yọjú ti yoo si di apàṣẹ-wàá

ti gbogbo agbaye ti a mọ̀ sí "asòdì-sí-Krist naa." eyi kì iṣe àlọ́. Nitootọ ni eyi yoo

ṣẹlẹ, nitootọ, a sì lè ti bẹrẹ si i ri awọn ami pé ó ti bẹrẹ si i ṣẹlẹ.

Bibeli nsọ fun wa pé lọjọ kan, ijọba agbaye kan yoo wà. Ní lọwọlọwọ a ní

ọpọlọpọ ijọba ti o yatọ. A ní Amẹrika, a ni Rọsia, a ni Ṣaina - gbogbo

wọn ni o jẹ orilẹ-ede ọtọọtọ, ti ó ni aṣẹ (boya ẹ ti gbọ́ ọrọ naa "ni aṣẹ") - gbogbo

orilẹ-ede ti o ní aṣẹ yii. Ó dara, lọjọ kan, Bibeli nsọ pe gbogbo awọn orilẹ-ede yẹn yoo

parapọ lati gbé ijọba agbaye kan kalẹ. Kete lẹyin ti wọn ba ti gbe ijọba

agbaye yẹn kalẹ, wọn yoo fun ẹnikan ni gbogbo agbara naa ti yoo jẹ́ olori ijọba yẹn,

ẹni yẹn ni a sì mọ̀ sí "asòdì-sí-Kristi" naa. Tani ó ti gbọ nipa asòdì-sí-Kristi naa ri?

Gbogbo eniyan ni ó ti gbọ́ ọrọ yii rí. "Asòdì-sí-Kristi" naa jẹ́ ọrọ inu Bibeli. Lemó-lemọ́ ni ẹ ó maa gbọ́

ti Bibeli nsọrọ nipa "ẹranko naa," abi "ẹranko naa ti ó wa lati inu okun," tabi "ẹranko naa ti ó ni ori meje

ati ìwo mẹwaa," tabi "ẹni ẹṣẹ" naa, abi "ọmọ egbe" naa, ṣugbọn Bibeli tún nlo

ọrọ naa "asòdì-sí-Kristi." Mo fẹ́ lati lo ọrọ naa "asòdì-sí-Kristi: o jẹ́ ọrọ ti o yé awọn eniyan,

ó sì jẹ́ ọrọ inu Bibeli. Mo fẹ́ fihan yin nibi ti Bibeli ti nmẹnuba ọrọ naa

"asòdì-sí-Kristi" nitori pé Bibeli nsọ fun wa pe ẹnikan nbọ lọjọ kan ti a pe ni

asòdì-sí-Kristi naa. Kí Jesu Kristi to pada de, ẹlẹtan kan yoo wà, èké Kristi kan.

Ṣé ẹ ri ohun ti mo nsọ? Asòdì-sí-Kristi naa jẹ ọkunrin kan tí ó npe ara rẹ̀ ni ipadabọ

Kristi, ṣugbọn oun jẹ ẹlẹtan. Ṣugbọn niwọn igba ti a ti nkọ awọn Kristiẹni bayii lati maa reti

Jesu lati pada wa nigbakuugba, ó jẹ́ pípé nitori pé ẹ sọ ẹni ti ẹ ro pe ó nfi ara han gan an -

asòdì-sí-Kristi naa. Ki lo de ti Bibeli npe é ni "asòdì-sí-Kristi"? Nitori pe ẹnikan mbọ ti a pe ni "asòdì-sí-Kristi"

(ẹyọ kan) ti yoo wi pe oun ni Jesu Kristi. Nigba ti asòdì-sí-Kristi naa bá nfi ara han ni àkókò ipọnju naa

ti ó sì nwipe, "Emi ni Jesu Kristi," wọn yoo gba a gẹgẹ bi mesaya wọn. Ọpọlọpọ eniyan yoo

kọni pé, "Ah, nigba ti Jesu Kristi bá mbọ ninu awọsanma, awọn Juu yoo dá a mọ lẹyin-o-rẹyin pé

oun ni mesaya wọn, wọn yoo si gbà á." Bẹẹkọ, wọn yoo gba asòdì-sí-Kristi naa!

Ohun ti Bibeli nsọ niyẹn. Jesu sọ pé:

(Johannu :) Emi wá li orukọ Baba mi, ẹyin kò si gbà mi: bi ẹlomiran ba wá

li orukọ ara rẹ̀, on li ẹnyin ó gbà.

Oluṣọ-agutan Anderson: Mo lero pé ète Satani pẹlu igbasoke ti ó siwaju ipọnju naa ni lati jẹ ki gbogbo eniyan

ni ero yii pé "Jesu Kristi nbọ nigbakuugba." A nreti

Jesu Kristi nigbakuugba! Ó lè dé lonii! Ó nbọ lonii!" ṣugbọn ni tootọ

ẹni ti o nbọ naa ni asòdì-sí-Kristi naa. Asòdì-sí-Kristi yii, nigba ti oun ba de, yoo jẹ

olori ijọba ayé-dọ̀kan ati ẹsìn ayé-dọ̀kan nibi ti ó ti npe ara rẹ̀ ni mesaya naa.

Ó nsọ ninu ẹsẹ ikejidinlogun ti ori keji iwe Johannu Kinni:

(I Johannu :) Ẹnyin ọmọ ni, igba ikẹhin li eyi: bi ẹnyin si ti gbọ́ pe Asodisi-Kristi

mbọ̀wá, ani nisisiyi Asodisi-Kristi pupọ̀ ni mbẹ; nipa eyiti awa fi mọ̀ pe igba ikẹhin li eyi.

Oluṣọ-agutan Anderson: Ṣe igba ti a kọkọ mẹnuba á yẹn jẹ́ ẹẹkan kan tabi ni amimoye igba? Nitori naa wọn ti gbọ pe asòdì-sí-Kristi

(ẹyọ kan) yoo wá. Nitori naa, asòdì-sí-Kristi ẹyọ kan ni o mbọ̀, abi bẹẹkọ? Ṣugbọn ṣe ko si ọpọlọpọ

asòdì-sí-Kristi nisisiyi gan an? Ohun ti ẹsẹ naa nsọ niyẹn. Awọn wo ni asòdì-sí-Kristi yii?

( Johannu :) Tani èké, bikose ẹniti o ba sẹ́ pe Jesu kì iṣe Kristi? Eleyi ni Asodisi-Kristi,

ẹniti o ba sẹ́ Baba ati Ọmọ.

Oluṣọ-agutan Anderson: Lati gbagbọ pe Jesu kì í ṣe Kristi naa, ẹ ni lati gbagbọ

pé Kristi kan wà tí kì í ṣe Jesu. Ọrọ naa "Kristi" tumọ si "Mesaya."

Bibeli nsọ ninu iwe Johanu, ori ikinni, ẹsẹ ikọkanlelogoji pé, "Awa ti ri Messia, itumọ̀ eyiti ijẹ,

Kristi." Nitori naa, Bibeli ntumọ ọrọ naa "Kristi" sí "Mesaya. A lè fi mejeeji paarọ ara wọn.

Nitori naa, ẹ jẹ ki nbeere eyi lọwọ yin: njẹ e le ronu nipa ẹsìn kan nibẹ̀ yẹn ti ó nsọ pe

mesaya kan wà ti ó nbọ, ṣugbọn kì í ṣe Jesu - Jesu kọ́ ni ẹni naa. Ẹsìn Juu nkọni

pé mesaya kan wà, ó dara, ṣugbọn kì íṣe Jesu ni. Wọn ṣì nreti

mesaya naa. wọn nsọ pé Jesu kọ́ ni mesaya naa, tí ó sì jẹ́ pé wọn ṣì nreti

mesaya naa. Bibeli nsọ pe wọn yoo gba asòdì-sí-Kristi gẹgẹ bi mesaya wọn.

Kristiẹni ajiyinrere ti ó gbagbọ pé Jesu lè dé nigbakigba, awọn ti a kò

gbala, awọn ti kò gba otitọ gbọ, ọpọlọpọ wọn ni a ó tanjẹ tí wọn yoo sì rò pé "Eyi

ni ipadabọ Jesu Krist lẹẹkeji! Lonii, awọn musulumi nreti ànábì nla kan

ati mesaya nla kan lati wá ti ó pọ̀ ju Mohammadu lọ. Aarẹ Ahmadinejad,

Aarẹ ilẹ Ìráànì - tani ó ti gbọ́ nipa rẹ̀ rí? Aarẹ Ahmadinejad sọrọ

ninu Àjọ Àpapọ̀ awọn Orilẹ-ede ní ọdun kan tabi meji sẹyin, nigba ti ó si ṣe bẹẹ, ó funni ni

alayé ranpẹ́ nipa ẹsìn Islamu.

Mahmoud Ahmadinejad: "Koko iṣẹ́-riran àwọn woolii jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo ati ọ̀kan naa. Iranṣẹ kọọkan

ti gbóriyìn fun iranṣẹ ti ó ṣaaju rẹ̀ ti ó si ti funni ni iroyin ayọ nipa iranṣẹ ti ó kàn

lati wá tí ṣe agbekalẹ ẹ̀dà ẹsìn naa ti ó jinlẹ̀ si i gẹgẹ bi okun eniyan

ni akoko yẹn. Ilana yii tẹ siwaju titi ti iranṣẹ Ọlọrun ti o kẹyin ti o ṣe agbekalẹ pípé

ẹsìn kan ti o ṣe àkópọ̀. Nimrọdu tako iwalaaye Abrahamu. Farao tako iwalaaye Mose,

olojukokoro si tako iwalaaye Jesu Krist ati iwalaaye Mohammadu - ìkẹ́ ati ọlà ki ó maa bá gbogbo

awọn ànábì wa."

Oluṣọ-agutan Anderson: O sì wipe Islamu gbagbọ pe Abrahamu jẹ ànábì nla. Mose jẹ

ànábì nla, nigba naa ni Jesu si wà. nigba naa ni Mohammadu si wà - tí Musulumi naa

si nmì ori rẹ̀ ki nlè maa gbọ́ ọ ni agbọye! Ohun ti Ahmadinejad sì kuku sọ

ni pé ọkọọkan ninu awọn gbé otitọ tí ó pọ̀ ju ti ẹni ti ó ṣaaju rẹ̀ lọ bí eniyan ti ṣetan

fun un. Wọn tubọ tàn imọlẹ ati afikun alaye ati afikun otitọ. Ó sọ pé ní

ọjọ iwaju ànábì miran yoo wá ti yoo tilẹ ju Mohammadu lọ ti yoo sì

gbé ipele imọlẹ ti o kàn wá. nitori naa Islamu nreti ki eniyan kan bi i mesaya wa.

Wọn nreti Lemọmu Mahdi.

Mahmoud Ahmadinejad: Ọlọrun o, jẹ ki dídé Lemọmu yá kánkán ki o sì fun un ni alaafia pipe

ati iṣẹgun, ki o sì ṣe wá ní sàábé rẹ̀, ati awọn ti yoo jẹrii si otitọ rẹ̀.

Oluṣọ-agutan Anderson: Awọn ẹlẹ́sin Buddha nreti ki Buddha Karun un dé. Awọn ti ó wa

ni ilẹ̀ Tibeti ti wọn ntẹle Dalai Lama: wọ́n gbagbọ pe Dalai Lama naa npada wá silé aye ni gbogbo igba

gẹgẹ bi elomiran - ẹmi inu Dalai Lama yẹn. Wọn yoo gbagbọ pé asòdì-sí-Kristi

ni ifarahan Dalai Lama tuntun. Awọn Musulumi yoo kà á sí Lemọmu Mahdi.

Awọn Kristiẹni yoo kà á sí ipadabọ Kristi lẹẹkeji. Awọn Juu yoo kà á sí

mesaya naa. Gbogbo awọn ẹsìn pataki yii yoo fara mọ́ ọ, awọn eniyan yoo si wipe,

Ṣé eyi ko wuyì bi a ti nparapọ lẹyin-o-rẹyin! A ngbe gbogbo aidọgba wa tì sí apa kan,

ọkunrin yii si buyaari tó bẹẹ!" wọn yoo si sìn ọkunrin yii. Ẹlẹtan yii, asòdì-sí-Kristi yii,

tí ó nbọwá. Ijọba agbaye yoo fi í sipò wọn yoo sì fun un ni gbogbo agbara,

wọn yoo si kede rẹ̀ gẹgẹ bi Ọlọrun. Wọn yoo kede rẹ̀ gẹgẹ bi ipadabọ

Kristi lẹẹkeji. Wọn yoo pa a. Bibeli wi pe oun yoo gba ọgbẹ́ aṣápa

ní ori rẹ̀, a ó wò ọgbẹ́ aṣápa rẹ̀ sàn, ara rẹ̀ yoo dá. nigba naa ni a ó

kede rẹ̀ gẹgẹ bí ipadabọ Jesu Kristi lẹẹkeji. A ó kede rẹ̀

gẹgẹ bi Ọlọrun ninu eniyan, gbogbo orilẹ-ede agbaye, ati gbogbo eniyan agbaye yoo sì

sìn ọkunrin yii. Gbogbo ẹsìn ni yoo gbà á gẹgẹ bi mesaya wọn, ṣugbọn

Bibli sọ pé a kò ní tan awọn ti a gbala jẹ. Iyooku gbogbo agbaye

yoo sìn in ti wọn yoo sì gbà á gbọ́ nitori pé oun yoo ṣe awọn iṣẹ iyanu, ni Bibeli wi,

oun yoo sì ṣe gbogbo iṣẹ́ amì yii, yoo si gbà

ijọba agbaye mọ́ra nigba miran ẹ ó gbiyanju lati kilọ fun awọn eniyan nipa ijọba agbaye-dọkan.

Ẹ ó gbiyanju lati kilọ fun wọn nipa awọn iṣẹlẹ kan ti a nri tí ó nṣẹlẹ nipa ti rírà ọja lailo owó

ni awujọ. Ọpọlọpọ Kristiẹni ni ó wà ti ó jẹ́ pé - ẹ bá awọn Kristiẹni sọrọ nipa agbaye kan ṣoṣo

abi ki ẹ ba wọn sọrọ nipa awujọ rírà ọja lailo owó ati gbogbo awọn oniruuru ojúkò ayẹwo wọnyi

ti a ngbé kalẹ ati bi ijọba ti di ti ọlọpaa, wọn yoo si sọ yin lorukọ gẹgẹ bi "elérò ọ̀tẹ̀."

Ó dá mi loju pé a ó ti pè yin ní elérò ọ̀tẹ̀ fun ọpọlọpọ ọdun.

Ọmọwé. Kent Hovind: Bẹẹni, ni ọpọlọpọ igba.

Oluṣọ-agutan Anderson: Ṣugbọn ṣe eniyan lè jẹ́ Kristiẹni ti ó gba Bibeli gbọ nitootọ ki ó sì sẹ́ pé

ijọba agbaye kan ṣoṣo yoo dé lọjọ kan?

Ọmọwé Kent Hovind: Mi ò lero pe ẹ lè ka Bibeli lairi otitọ naa pe ó

ti jẹ́ ète Satani ni gbogbo igba ṣe akoso agbaye gẹgẹ bi ti eré ori itage kan, ó sì nfẹ́

ijọba agbaye kan ṣoṣo. Ó fẹ́ di Ọlọrun.

Abala - Ami Ẹranko naa

Oluṣọ-agutan Anderson: Nigba ti ọkunrin yii bá nṣakoso gbogbo agbaye, oun yoo paṣẹ pe ki gbogbo eniyan

gbà ohun ti a pè ní "ami Ẹranko naa." tani ó ti gbọ́ nipa ami ẹranko naa ri?

Bibeli wipe ami ẹranko naa yoo jẹ́ nnkan kan ni ọwọ́ ọtun yin abi ni

iwaju ori yin, kò sì sí ẹni ti yoo lè rà tabi tà laini ami yii.

Awọn lè wá ti kà nipa eyi fun ọgọrun ọdun diẹ sẹyin ki wọn si wipe, "Bawo ni ẹ ó ṣe lè ṣe iyẹn? Bawo ni

ẹ ó ṣe lè maṣe jẹ́ ki awọn eniyan rà tabi tà laini ami yii? Ẹ ò tilẹ̀ ṣe

kó owó jade?" Ẹ wò bí imọ-ẹrọ ti ri. Owó yii ti mo kó lọ́wọ́

owó ti ilé ifowopamọ ijọba apapọ tẹ̀, jẹ́ beba lasan. Kò niye lori. Ko ni

adiyele ninu. Nigba ti ẹ ba ri awujọ ti a ti nraja lailo owó tí ó ntẹsiwaju - nṣe ni a tubọ nsare lọ

kuro ninu lilo owo…

Ọkunrin ori ẹro amohun-maworan: Igba kan yoo wa ti owo ti a nna yii ko ni si mọ́.

Olootu Iroyin: Nitori naa owó oni-beba ti di ohun itan o ti lọ?

Ọkunrin ori ẹro amohun-maworan: Ìdá marun-din-lọgọrun ninu ọgọrun kara-kata ni Amẹrika abi ju bẹẹ lo ni kò ni nnkan íṣe mọ́

pẹlu owó oni-beba abi owó ẹyọ.

Obinrin Oniroyin: Njẹ́ ẹ ti dà á rò rí boya ni ọjọ kan ojulowo owó kò kàn ní í sí mọ́?

Ó jẹ́ otitọ ti awọn kan sọ pé a gbọdọ fi ara mọ́. Owó oní-beba ati owó ẹyọ ti di ohun idiwọ kan.

Alaṣẹ ilẹ eniyan dudu: Ilana naa ni pé a ni lati gbe ọrọ̀-ajé yii lati eyi ti o nlo owó

sí ti kii lo owó. Eyi kàn awọn ilé ifowopamọ. Eyi kan awọn ile-iṣẹ ẹrọ ibanisọrọ.

Ó kàn awọn ti o npese awọn ẹrọ ti ó npọ̀ owo ati awọn ojuko kara-kata. O kan ayipada àṣà

Olootu Iroyin: Kinni ẹ npè ni owó gan an lode oní? Ṣé ẹkunwọ́ owó ẹyọ ati beba ni?

Abi awọn kaadi ti gbòde. Ti irú owó tí a mọ̀ si ti nkogbá silé,

Bí iwe sọwé-dowo?

Ọmọwé Kent Hovind: Ẹ jẹ́ ki a gba pé gbogbo ile itaje ilú yin sọ pe, "Ẹ gbọ́, a kò gba owó mọ́,"

ki a si gba pe wọn wipe, "A kò ni gba iwe sọ̀wé-dowó mọ́ abi kaadi ìsanwó nitori pé

gbájúẹ̀ ti pọju - ọpọlọpọ kaadi isanwó ni wọn ti jí lọ tí ọpọlọpọ iwe sọ̀wé-dowó kò sì dowó. Ó

gbọdọ jẹ́ kara-kata ti ẹrọ."

Oluṣọ-agutan Anderson: Let's face it: the paper money is not really worth anything anyway.

Ẹyọ beba kan ni. Ó tun lè jẹ́ owó Gbogbo-niṣe. Kiiṣe goolu. Kiiṣe

fadaka. Kò ni iye kankan lori. Nitori naa, wọn kọkọ jẹ́ kí ó mọ́ wa lara lati lò

awọn ẹyo beba ti kò wulo. Lonii mo lè ṣe paṣi-paarọ ẹyọ beba kan fun awọn ọja,

ṣugbọn ti ẹnikan ba sọ lọla pé, "Owó yẹn kò ni iye kankan lori," nigba naa ni o jẹ́ pe

kò ní ní iye kankan lori. Njẹ́ ẹ ranti awọn Ipinlẹ Alajọṣepọ ti Ilẹ Amẹrika? Njẹ́ ẹ ranti owó ilẹ alajọṣepọ?

Awọn eniyan kó owó ilẹ alajọṣepọ pamọ sinu timu-timu. Ki lẹ ro, kò niye lori

rara. Ó dara wọn lè ṣe iyẹn si ẹ̀yin naa, kí wọn si wipé, Ó dara, owó oni-beba yin

kò dara. Gbogbo rẹ̀ sá wà ninu àṣùwọ̀n yin. A so gbogbo rẹ̀ pọ̀ mọ́ àṣùwọn Facebook ati ìkànnì Youtube

ati gmail yin, ó si wuyi pupọ nitori kò sí pé a nṣerú sí ami idanimọ. Ẹ kò ní í

ki ẹ maa daamu nipa gbigbagbe ọ̀pọ́ọ̀ yin sile. Kò nilo pé ẹ ndaamu nipa gbigbagben kaadi

jiji kaadi yin lọ. Gbogbo rẹ̀ ni kò sá nilò owó r ara." A lè dari oogun nitori pé

kò nilò pé kò ní sí ọna lati ṣeto kara-kata ti ó la owó lọ. Ó wà fun didena iwà ọdaran.

Obinrin Oniroyin: O jẹ́ imọ̀-ẹrọ igbalode ti ó fe gbode lorukọ

ere-sisa ati itura. Ẹ ó lè ra ohunkohun lati burẹdi si ọtí tí ẹ bá fẹ́

lati fun ile-itaja naa ni ami idanimọ yin ti o ga julọ.

Ọkunrin lati ẹgbẹ ẹtọ́ ọmọniyan: Ó maa nkọmi lóminú.

Obinrin Oniroyin: Ni kete ti a ba ti ṣe ayẹwo awọn eso yin, kini ẹ ó wá ṣe? Ẹ ó nà ika yin aarin

sí ẹrọ ti ó njuwe awora, ẹ si ti sanwó niyẹn ni iṣẹju aaya mẹta pẹlu ifọwọkan

orí ìka. A npè é ni ijuwe: ọna ti imọ-ẹrọ ti a fi nda yin mọ̀ eyi ti ó dá lori idayatọ yin

nipa àjẹbí.

Ọkunrin lati ẹgbẹ ẹtọ́ ọmọniyan: Ẹ maṣe jẹ́ ki eyi mú yin mọlẹ nitori itura kan.

Oṣiṣẹ́ QT nigba kan: Ẹ mọ pe, oni ìka titẹ̀ ni, ọla ki a fi nnkan há ara. boya iyẹn

ni ó nlana fun ami ẹranko naa.

Obinrin Oniroyin: Ọkunrin yii fi iṣẹ rẹ̀ silẹ ni ipo ọga ni Quik Trip nigba ti ile-itaja naa

sọ fun u pe ó gbọdọ fi ìka rẹ̀ kàn agogo kí ó tó wọṣé ati kí ó tó lọ silé.

Oṣiṣẹ́ QT nigba kan: Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má pọn dandan lonii, ta ló mọ ilẹ̀ ti yoo mọ́ lọ́la.

Obinrin Oniroyin: Awọn onimọ̀ sọ pé ijuwe ti fẹ́ borí gbogbo ẹka ọrọ aje wa

ati igbe-aye wa.

Obinrin Oniroyin: O fi ìka rẹ sinu rẹ̀, orukọ mi sì jade, ó si ti ri gbogbo

ifitonileti mi.

Obinrin Oniroyin: Ó sí̀ yá tó bẹyẹn?

Obinrin ori ẹrọ amohun-maworan: Ó yá jọjọ.

Obinrin Oniroyin: Abi ẹ fẹran rẹ̀?

Obinrin ori ẹrọ amohun-maworan: Mo nifẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Obinrin Oniriyin: Awọn ni gbogbo agbaye nlo ti nlo ijuwe tẹlẹ. Ijọba Amẹrika, awọn ilé-iṣẹ ọkọ ofurufu ,

awọn ilé-epo - Walt Disney paapaa nlo imọ̀-ẹrọ tí ó lè rí iṣan-ara awọn onibàára

afi ẹni ti ó bá mú iwe irinna ojoojumọ́ dani.

Oluṣọ-agutan Anderson: Ijọba agbaye kan ṣoṣo yii yoo lagbara to bẹẹ ti ó fi jẹ́ pé yoo lè

paṣẹ pé kò sí ẹnikan lori ilẹ̀ aye yii ti yoo lè rà tabi tà laini

ami ẹranko naa. O wá dun mọni pé Bibeli Ẹ̀dà ti Ọba Jakọbu sọ ọ́ yekeyeke pé

ami ẹranko naa - ami yii tí a ó beere lọwọ yin lati rà ati lati tà - yoo

wà NÍ ọwọ ọtun wọn abi NÍ iwaju ori wọn. Eyi lè jẹ́ irú nnkan kan ti a lè fi hà inu ara

tí ó jẹ́ pé lati rà abi tà, ẹ ó kàn ní lati yẹ̀ ìfihára yii wò. Ohun tí yoo

ṣẹlẹ ní ọjọ́ kan ni pé wọn yoo sọ pe, "Owó oní-beba yii - Ogọ́run dọla yẹn ninu

apò yin - kò niyelori. Ẹ ni lati ṣe ayẹwo kí ẹ tó sanwo. Ti ẹrọ ni bayii. Ẹ ó lọ sí

ṣọọbu eléso, ẹ ó tẹ̀ eléso laago, kí ẹ sì *sàpẹ* lasan. Tí ẹ kò ba ní

ọwọ́, kò séwu, a lè fi sori yin nitori pé gbogbo eniyan ni ó ni ori! Ẹ ó kàn

*sàpẹ* kí ẹ jade nibi ijade. gbogbo owó naa yoo kan jẹ́ ti ẹlẹ́rọ,

ó si ti nṣẹlẹ̀ bẹyẹn. Awọn ẹrọ alágbèéká ti bẹrẹ si í ni ohun iṣayẹwo. Nitori naa, ẹ jẹ́ ki a sọ

pé paṣipaarọ awọn ọja laarin eniyan meji. Ó dara, iyẹn yoo jẹ́ dọla mẹwaa ati abọ̀.

Ẹ tẹ siwaju kí ẹ si fun mi ni ọwọ ọtun yin ki nle fi ẹrọ ibanisọrọ igbalode mi yẹ̀ ẹ́ wo. *sàpẹ*

Ó dara, nisisiyi mo ṣẹṣẹ gbowo ninu aṣùwọn mi. Ah, ẹ ṣẹṣẹ kọ ọmọ mi ọkunrin ni duuru titẹ. Ẹ jẹ́ kí

n sanwó fun yin. *sàpẹ* Ẹ ronu nipa rẹ̀ nisisiyi: a lè lo ẹrọ ibanisọrọ naa lati ṣe ayẹwo ami

ẹranko naa, ẹ kò sì lè rà abi tà laisi i.

Obinrin Oniroyin: Ninu iroyin ìṣègùn ni aṣalẹ yii, ìfihára bíi woro raisi lè gbà

ẹmi yin la.

Olootu Iroyin: Ọdun naa jẹ́ . Wọn gbé yin digba-digba lọ si ilé iwosan laimọ̀ ibi tí ẹ wà laisí kaadi idanimọ̀ abí

itan nipa ilera yin, ṣugbọn a dupẹ lọwọ ìfihára kekere kan labẹ awọ yin, gbogbo rẹ̀ wà nibẹ̀. Itàn arosọ sayẹnsi

ogun ọdun sẹyin, ṣugbọn ó di otitọ ti ijúwe lonii.

Ọjọgbọn: Mo ro pe ó ṣeeṣe lati tú wa silẹ̀ patapata kuro ninu awọn ọ̀pọ́ọ̀ ati kọkọrọ nipa

imọ̀-ẹ̀rọ ti ijuwe tí ó bá jẹ́ pé ohun tí awọn eniyan nfẹ́ niyẹn ni ọdun mẹwaa sihin.

Olootu Iroyin: Ipenija naa ni lati daabo bò aṣiri wa ninu aye ọdaju igbalode yii.

Olootu Iroyin: Imọ-ẹrọ tuntun ti ìfihára kekere ti wá njẹ́ kí ó ṣeesẹ fun awọn oṣiṣẹ pajawiri

lati wadii nipa itan ilere yin nipa fifi ọwọ tẹ̀ ẹrọ a-yara-bi-aṣa.

Oniṣegun lati Harvard: Ọpọlọpọ oniṣegun pajawiri ni ó ti ní lati ṣiṣẹ́ abẹ lailaju. A gbọdọ gbé igbesẹ lori eto iṣegun

laimọ irú oogun tí ẹ nlò abi ohun ti kò bá yin lara mu.

Olootu Iroyin: Oniṣegun lati Harvard nsọ pé ìfihára Idanimọ ti ó mbá ẹrọ a-sọrọ-ma-gbesi ṣiṣẹ yii lè yanju

iṣoro yẹn. O ti fi í sinu apa rẹ̀ ọtun. Ẹrọ ayẹwo kan yoo wò nọmba

idanimọ kan. Awọn wóró nọmba mẹrindinlogun yẹn ni a ó tẹ̀ sí oju òpó kan ti aabo wa lori rẹ̀ nibi ti itan iṣegun rẹ̀

ti wà ni ipamọ. Oṣiṣẹ EMT nsọ pé ìfihára naa lè ràn awọn oṣiṣẹ pajawiri lọwọ.

Oṣiṣẹ EMT: Ọkan lara awọn nnkan pataki ni igba tí ẹ bá ni alaisan yoowu ti ó bá ní aisan ìjayà nibi tí

wọn yoo ti wá, tí wọn kò si ní lè ṣalaye nipa ara wọn abi itan iṣegun

wọn.

Olootu Iroyin: Oniṣegun lati Harvard nsọ pé awọn anfaani rẹ̀ yè kooro.

Oniṣegun lati Harvard: Mo maa ngun oke, mo si gbagbọ pé ti mo ba jabọ lẹ́sẹ̀ oke, tí ẹ sì

ri mi ti ni ò mọ ibi ti mo wa, itura pé ẹ lè ṣe ayẹwo mi kí ẹ sì fi inu ro ẹni ti mo jẹ́ rekọja

ijaya mi fun aṣiri mi.

Olootu Iroyin: A fi ìfihára naa sinu ike tí ó sì tobi tó wóró

irẹsi. A ó ṣe eto naa pẹlu ikùnlóorun tí ó sì jẹ́ pé kò sí títa ríro.

Oniṣegun lati Harvard: Nṣe ni ó dabí fífi abẹrẹ iranṣọ gunni.

Olootu Iroyin: Ṣugbọn ní ti eyi, ó nsọ pé fífi nnkan pamọ sara ẹni jẹ́ nnkan

tí ó dara.

Olootu Iroyin Ọkunrin: Bí ó ti nbẹrẹ niyi: ologbo yii niyi, lẹyin ọdun marun, a si rí i

pé ó pada dé. Ẹnikan wá sọ pé, “Ẹ mọ pé ó dara tó fun ologbo, mo ti ní

iyá ati baba nilé tí ó sì dabi ẹni pé baba maa nrin kiri nigba miran tí a sì lè fi ìfihára kekere

ti itan iṣegun rẹ̀ wà nibẹ tí nnkan ba ṣeeṣi ṣẹlẹ. Ó wù etí gbọ́" nigba naa ni ẹnikan

wipe, “Ó dara, tí ó bá dara to fun ologbo mi, ó dara to bakan naa fun iyá agba ati baba agba,

ọmọ mi jòjòló nkọ́?" Kò sí ìtani-lólobó awọn ajọmọgbé mọ́. Kò sí ifoya mọ́ nipa

ọmọ ti a jí gbé. Nigba naa ni a ó sọ pé, "Ó dara, ṣẹ́ ẹ dá nnkan mọ̀? Boya ó ƴe kí A ní wọn.

Lára ìfihára yẹn, a ó sì ní ohun gbogbo. Kaadi isanwó, iwé àṣe ìwakọ̀. Ẹ ronu nipa

rẹ̀. Awọn kaadi isanwó ọkọ̀. Kò sí ọ̀pọ́ọ̀ mọ́. Ẹ ronu nipa eyi, ẹ kò ní kó kọkọrọ kaakiri mọ. Nitori naa

ibeere tí mo fẹ́ kí gbogbo eniyan ninu ile beere ni pé: Ṣé ero rere niyẹn? Nitori ibẹ̀ yẹn

ni ó kàn tí a nlọ.

Olootu Iroyin Obinrin: O ti fi ara pẹ́ itan jù fun mi, mo nsọ iyẹn fun yin.

Olootu Iroyin Ọkunrin: Nihin ló wà! Nihin ló wà.

Olootu Iroyin Obinrin: Mo mọ̀ pé ihin ló wà tí ó sì wà pẹlu ẹran ọsìn ní ọna tí ó sì ní gbèdéke ṣugbọn fun awọn eniyan…

Olootu Iroyin Ọkunrin: Ṣugbọn ọmọde ni yin…

Olootu Iroyin Obinrin: Ọmọde ni yin…mo ní kí ẹ sojí...

Steven Anderson: Awọn eniyan ni atijọ ti lè dà á rò pé, “Bawo ni a ó ṣe ṣe eyi?

Bawo ni ẹ ó ṣe dí awọn eniyan lọwọ ninu tita ati rira ti wọn kò bá ni ami?”Ṣugbọn a nrí But we see

imọ-ẹrọ tuntun bayii tí ó njẹ jade tí yoo jẹ́ kí ó rọrun jọjọ lati maṣe jẹ́ kí ẹnikẹni rà

abi tà laini ami yii. Ẹ si fi inu rò nnkan? Awọn eniyan tí ó pọju ni ó ní onjẹ tí ó tó fun ọjọ meje péré

ninu ile wọn abi onjẹ ọjọ mẹwaa ninu ile wọn, nitori naatí ẹ kò bá lè rà abi tà

ẹ ó wà ninu aye inira. Bibeli sì nsọ ṣaaju pé ofin

kan yoo wà tí ó nsọ pé bí ẹ kì yoo bá sìn asòdì-sí-Kristi naa a ó pa yin. Ọkunrin yii

pọ̀ jọjọ, ó nṣe ọpọlọpọ ohun nla, ó nkó awọn eniyan jọ. Ẹyọ

akopọ̀ kan: Ẹ dara pọ̀ abi kí a pa yin. Tí ẹ bá sì gbọ́ nipa iyẹn, nigba tí ẹ bá wò

iyẹn, boya ẹ ó sọ pé, Ó dara nigba yẹn, mo lérò pé gbogbo wa

tí a jẹ́ onigbagbọ ni a ó kú, awọn tí ó gba Kristi gbọ. mo lero pé a ó bẹ́ ori gbogbo wa. Tí

Bibeli sì nsọrọ nipa ori bibẹ. Nṣe ni a ó bẹ́ ori gbogbo wa. Ṣugbọn nihin ni

nnkan naa wa. Ti ́ a bá fi aaye gba eyi lati tẹ̀ siwaju, ẹ tọ́nà, gbogbo onigbagbọ ni a ó pa. Nitori pé

ẹ rò ó wò, ẹ wo imọ-ẹrọ, ẹ wò awọn ẹrọ iyaworan tí ó nṣọni tí ó nyọju

nibi gbogbo, awọn ẹrọ oju ofurufu. Awọn ọlọpaa ti wa nlò ọkọ ofurufu ti eniyan kii tukọ rẹ tí ó ní ẹrọ ayaworan lati kaakiri

ati lati ṣọ́ yin. Njẹ́ ẹ ti ri iyẹn? Awọn ọkọ ofurufu ti eniyan kii tukọ rẹ̀ tí a fi nṣọ́ni. Wọn ti wá ngbé ẹrọ gbohun-gbohun kalẹ̀

sí awọn igun igboro nibi tí wọ́n ti lè tẹti sí ohun tí ẹ nsọ. Ó sì dabi

iwe akagbadun nì “.” Bí orilẹ-ede wa ti nlọ niyẹn, sibi tí yoo ti dà

awujọ aṣóni patapata. Nṣe ni ẹ kàn dede nwọnu ọkọ ofurufu tẹlẹ. Bayii a ní lati

ṣe yín ní iwọsi lati ọdọ ajọ alaabo irinna. Bayii ẹ nilati kọja nibi ẹrọ aṣayẹwo ara. Bayii ẹ ní lati

ṣe ayẹwo. A ni lati wá gbogbo ara yin. Ẹ gbọdọ ní iwe idanimọ pẹlu yin ní

gbogbo igba tí awọn ọlọpaa sì nbeere ni gbogbo igba pé, “Iwe idanimọ yin nkọ? awọn iwe yin dà? Awọn iwe yin

kò pé!” Iyẹn sì ni orilẹ-ede tí a ngbe ninu rẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Nitori naa eyi yoo si

tẹ̀ siwaju debi pé yoo ti nira gan an lati bọ́ ninu ẹwọn

aye yii. Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí nsọ eyi: Kì íṣe gbogbo wa ni a ó pa. Ọpọ;ọpọ ni a ó pa, ẹ maṣe

ṣì mi gbọ́. Ọpọlọpọ Kristiani ni a ó bẹ́ lori nitori Kristi. Ṣugbọn ng ó

sọ eyi: A kò ní pa gbogbo wa nitori pé a ó ké eyi kuru. Bibeli sì nwipe:

(Matteu :) Bi kò si ṣepe a ké ọjọ wọnni kuru, kò si ẹda ti iba le la a;

ṣugbọn nitori awọn ayanfẹ li a o fi ké ọjọ wọnni kuru.

Oluṣọ-agutan Anderson: Bibeli sì nwi pe laarin eyi, Jesu Kristi yoo pada dé.

Ẹ ranti pé a sọrọ ṣaaju nipa ipadabọ Kristi lẹẹkeji. yoo pada wá. ní akoko gan an

tí wọ́n bá ró pé wọ́n ti bori ẹsìn Kritstiani, wọ́n ti gbà ijọba agbaye wọn, wọ́n ti

gbà ijọba agbaye wọn kan ṣoṣo pẹlu Satani gẹgẹ bi olori rẹ̀, jesu Kristi mbọ̀wá ninu awọsanma

iyẹn sì ni igba ti igbasoke bá nwaye tí ó sì jẹ́ igba tí ó nbẹrẹ sí í rọjò

ibinu rẹ̀ sori aye yii. Ẹ sì lè nipa rẹ̀ ninu Ifihan. Yoo maa yí

omi pada sí ẹjẹ̀. Yoo maa jó awọn igi ati koriko run. Yoo maa rán

awọn esú yii wá lati ọrun apaadi ti wọn yoo maa fi ìrù wọn ṣán eniyan bii ti akeekee.

Tí ẹ kò bá ti kà iwe Ifihan, mo rọ̀ yin gidigidi. Ẹ má sì ṣe kà

Ẹ̀dà ti Agbaye Tuntun. Ẹ kà Ẹ̀dà ti Ọba Dafidi, ṣé ẹ gbọ́? Tí ẹ ó bá wá akoko lati kà

á, kí ló dé tí ẹ kò kà ojulowo? Ẹ maṣe gba idiwọ. Ẹ wò ori ikẹtala, ẹsẹ ikinni:

(Ifihan :) Mo si duro lori iyanrìn okun, mo si ri ẹranko kan nti inu okun jade wá

o ni ori meje ati iwo mẹwa, ati ade mẹwa lori awọn iwo na, ati li awọn ori rẹ̀

na ni orukọ ọrọ-odi.

(Ifihan :) Ẹranko [Asòdì-sí-Kristi] ti mo ri na si dabi ẹkùn, ẹsẹ rẹ̀

si dabi ti beari, ẹnu rẹ̀ si dabi ti kiniun: dragoni na [Satani]

si fun u li agbara rẹ̀, ati itẹ rẹ̀, ati ọlá nla.

Oluṣọ-agutan Anderson: Nitori naa, ẹranko yii tí a juwe, Bibeli nsọ pé dragoni naa ni ẹni tí ó fun

u li agbara tí ó sì fun u ni itẹ́ rẹ̀ tí ó sì fun u ní aṣẹ. Ẹ wò ẹsẹ ikẹta:

(Ifihan :) Mo si ri ọkan ninu awọn ori rẹ̀ bi ẹnipe a sá a pa, a si ti

wo ọgbẹ aṣapa rẹ̀ na san, gbogbo aiye si fi iyanu tẹle ẹranko na. Nwọn si foribalẹ fun dragoni na

nitori o ti fun ẹranko na ni ọla: nwọn si foribalẹ fun ẹranko na, wipe, tali o dabi

ẹranko yi? tali o sile ba a jagun? A si nfun u li ẹnu

mã sọ ohun nla ati ọrọ-odi; a si fi agbara fun u lati ṣe bẹ ẹ ni oṣu

mejilelogoji.

Oluṣọ-agutan Anderson: Ṣé oṣu mejilelogoji wá ntọka sí akoko ati awọn akoko ati ilaji

akoko ati ẹgbaafa ọjọ́ ati mẹfa? Ẹ wò bi awọn nnkan yii ṣe wọnu ara wọn? Ó nsọ ní ẹsẹ

ikẹfa:

(Ifihan :) O si yà ẹnu rẹ̀ ni isọrọ̀-odi si Ọlọrun, lati sọ ọrọ-odi si

orukọ rẹ̀, ati si agọ́ rẹ̀, ati si awọn ti ngbe ọrun.

Oluṣọ-agutan Anderson: Ẹ kiyesi eyi. Ẹsẹ ikeje. Nihin ni kọkọrọ naa wà:

(Ifihan :) A si fi fun u lati mã ba awọn enia mimọ́ jagun, ati lati ṣẹgun

Oluṣọ-agutan Anderson: Ṣé a kò ti wá rí i ninu ori ikejila ẹsẹ ikeje pé ète dragoni naa ni lati

wọn: a si fi agbara fun u lori gbogbo ẹya, ati enia, ati ède, ati orilẹ.

bá awọn tí ó gbà Kristi gbọ́ tí wọ́n sì npa ofin Ọlọrun mọ́ jagun? Nihin ó

nsọ pé a fun u lati bá awọn eniyan mimọ jagun - Ẹ kiyesi eyi - lati ṣẹgun

wọn. tani yoo borí ninu ogun yii laaarin awọn eniyan mimọ ati eṣu lori ilẹ̀ aye yii?

Eṣu ni. Ó sọ pé oun yoo bá awọn eniyan mimọ jagun ti yoo si bori wọn. Gẹgẹ bi

Iwe Ifihan ori ikẹtala, afojusun asòdì-sí-Kristi ni lati bá awọn eniyan mimọ jagun. Nitori naa kò fẹ́ kí

Kristiani gbà ami eranko naa lati yẹra fun inunibini. Ó nfẹ́ kí Kristiani kọọkan

kú. Ẹ nsọ pé, "Ó dara iyẹn nbani ninu jẹ́." Ó dara, ẹ sá kà á dé opin iwe naa

ẹ ó sì rí ẹni tí ó ṣẹgun nikẹyin. Eyi kàn jẹ́ ijakulẹ igba diẹ ninu ori ikẹtala. Ṣugbọn

ó nsọ ní ẹsẹ ikeje pé:

(Ifihan :) A si fi fun u lati mã ba awọn enia mimọ́ jagun, ati lati ṣẹgun

wọn: a si fi agbara fun u lori gbogbo ẹya, ati enia, ati ède, ati orilẹ. Gbogbo awọn ti ngbe

ori ilẹ aiye yio si mã sin i, olukuluku ẹniti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe iyè

Ọdọ-Agutan ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye.

Oluṣọ-agutan Anderson: Nitori naa, ọkunrin yii ti a npè ni ẹranko naa, ọkunrin yii ni agbara lori gbogbo

ẹyà, eniyan ati edè, afojusun rẹ̀ ni lati bá awọn eniyan mimọ jagun ti Bibeli si

nsọ pé gbogbo eniyan lori ilẹ̀ aye yoo sìn í. Ẹ duro na. Rara, kò maa sọ bẹẹ. Ó nsọ pé

awọn tí yoo sin í ni gbogbo eniyan lori ilẹ aye ti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe iye

Ọdọ-Agutan tí a pa lati ipilẹsẹ aye. Nitori naa ẹ jẹ́ kí nbeere eyi lọwọ yin. Ṣé awọn tí

orukọ wọn WÀ ninu iwe iye nsin i? Rara. Ó dara, Bibeli nsọ pé oun yoo

ṣe é gbagbọ ti yoo sì kúná tó bẹẹ debi pé yoo tan awọn ayanfẹ jẹ ti ó bá ṣeeṣe. Ṣugbọn Ọlọrun kò

ní fi aaye gba ọkunrin yii lati tan awọn ti a gbala jẹ. Nitori naa gbogbo eniyan tí ó

bá ti di ẹni igbala nitootọ, awọn tí ó ti wọlé nigba igbasoke tí ó ṣaaju ipọnju paapaa, nigba ti wọn bá bẹrẹ

sí í rí i tí ó nṣẹlẹ, abi kí á ní ireti pé tí wọn bá rí fọ́nrán yii, wọn yoo sọji pé, “Ẹ duro

ná. Eyi nṣẹlẹ. Asòdì-sí-Kristi naa niyi. Mi ò lè fi ara mọ́ eyi. Kò yẹ kí nsìn

ọkunrin yii. Kì íṣe ojulowo Kristi niyi. Nitori naa a ó pa ẹnikẹni tí kò bá ní sìn í.

Ẹnikẹni tí kò bá sì ní sìn í kò lè rà tabi tà. Kì í kàn án ṣe pé ẹ ó

lọ sí Walgreen lati lọ gba ami ẹranko naa. Kì í ṣe nnkan tí ó jẹ́ pé

ẹ ó kàn fi ara hàn ni ile ifiweranṣẹ pé “Ó dara, njẹ́ mo lè rí ìfihára temi gba ki nlè rà tabi tàl?” Rara,

Bibeli yè kooro. Ẹ gbọdọ sin asòdì-sí-Kristi naa kí ẹ tó lè gbà ìfihára naa. Nisisiyi

lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin gan an, ẹrọ olóòótọ wà. nisisiyi wọ́n nṣẹ ẹrọ tí ó lè ṣe ayẹwo ọpọlọ. Mo

gbagbọ pé boya lati lè gbà ami ẹranko naa, ẹ ó ní

láti sìn asòdì-sí-Kristi naa kí ẹ sì jẹ́jẹ̀ẹ́ ijoloootọ labẹ asòdì-sí-Kristi naa tí oun yoo si mọ̀ boya ẹ

nsọ otitọ.

Olootu Iroyin: Itan imọ sayẹnsi ti wà. Ọjọ ọla ti dé bayii

Oluṣọ-agutan Anderson: Iyẹn nikan kọ́, ṣugbọn tí ẹ bá ronu nipa rẹ̀, igboke-gbodo ọkọ̀ ti wá

wà labẹ akoso tó bẹẹ. Awọn ojuko ayẹwo wa loju popo fun igbiyanju lati wà ọkọ̀ tí ẹ bá sì

gbiyanju lati wọ̀ ọkọ̀ ofurufu, ajọ alaabo irinna yoo mú kí ẹ kọja lara ẹrọ tí ó nṣayẹwo ihooho ara nitori naa ó sì

dabi ẹni pe a ti ngbe opó ìsakoso kalẹ kí ẹ má bà

lè ṣe ohunkohun ni awujọ ayafi tí ẹ bá fi ori balẹ fun ẹranko yii ki ẹ sì sìn ẹranko naa

kí ẹ sì gbà ami naa.

Kent Hovind: Bẹẹ gẹgẹ ni o ri. A ó sì sọ wá di ẹni ibi. Jesu sọ yekeyeke

pé a ó koriira awọn ọmọ ẹyin oun nitori orukọ oun. Ẹnikẹni ti ko ba fi ọwọ so ọwọ pọ pẹlu

eto iyanu tuntun ti agbaye yii ti wọn npete rẹ̀ ni a ó kà sí ọta.

Fun apẹẹrẹ, pẹlu ile-iwe, tí ẹ bá lọ fi ọmọ yin sí ile iwe jẹle-sinmi

ti wọn sì wipe ẹ kò lè wá sile iwe naa ayafi tí ẹ bá gba abẹrẹ ajẹsara. Ó dara, tí ó bá jẹ́ pé

ẹ ní ikorira fun abẹrẹ ajẹsara nkọ tí ẹ sì wipe, “Ẹ gbọ́, mo lero pé eyi lè sọni di dindinrin. Ó lè

maa fa ọpọlọpọ nnkan. Mi ò mọ̀, ṣugbọn mi ò fẹ́ ta tẹtẹ. Mi ò sì

rí ibamu abẹrẹ ajẹsara ninu iwe mimọ nibi ti e ó ti fi majele diẹ̀ sí agọ́ ara yin lati

ní ajẹsara fun eyi tí ó pọ̀ jù bẹẹ.”

Oluṣọ-agutan Anderson: Bẹẹni, bẹẹni.

Kent Hovind: Otitọ naa ni pe, ile iwe naa sọ pé ẹ kò lè wá laigba abẹrẹ ajẹsara

nitori naa nisisiyi ẹ lè yàn. Ṣé ẹ ó tẹle ohun ti ẹ gbagbọ ni abi ẹ ó tẹriba tí ẹ ó sì

fun ọmọ yin ni abẹrẹ ajẹsara nitori itura? Yoo jẹ́ ọkan naa pẹlu ami ẹranko naa. Ó

rí bakan naa ni ọgọrin ọdun sẹyin pẹlu nọmba igbaye-gbadun. Awọn eniyan lodi sí

nini nọmba kan. “Ah, orukọ ni mi.” Nigba naa ni wọn fi pẹlẹ pẹlẹ de ibi

ti gbogbo eniyan ti ni ti wọn kò sì tilẹ ronu nipa rẹ̀ mọ́. Ṣé iyẹn ni igbesẹ̀ kinni, ikeji, abi ikẹta

si afojusun ikẹyin ti sisọ gbogbo agbaye di ijọba kan?

Oluṣọ-agutan Anderson: A lé Satani kuro ni ọrun. Ó mọ pé akoko kukuru ni oun ní. Ó nlọ lati

bá awọn onigbagbọ ati awọn eniyan mimọ jagun. Kinni ó sì nṣe? Ó nṣe é nipa fifi

ẹnikan sori oyè, abi kò maa ṣe bẹẹ? Dragoni naa fun un ni agbara rẹ̀. Ó fi ẹnikan sipo lori

gbogbo agbaye, lori gbogbo ẹya ati gbogbo ede. Ẹni yii yoo si ja ogun eṣu

lodi sí awọn eniyan mimọ. Bibeli nsọ ni ẹsẹ ikọkanla pé:

(Ifihan :-) Mo si ri ẹranko miran goke l ati inu ilẹ wá, o si ni

iwo meji bi odo-agutan, o si nsọ̀rọ bi dragoni. O si nlò gbogbo agbara ẹranko

ekini niwaju rẹ̀, o si mu ilẹ aiye ati awọn ti ngbe inu rẹ̀ foribalẹ fun ẹranko ekini

ti a ti wo ọgbẹ aṣápa rẹ̀ san.

Oluṣọ-agutan Anderson: nitori naa ọkunrin naa nbeere fun ijọsìnfun. Ó nsọ ninu ẹsẹ ikẹtala pé:

(Ifihan :-) O si nṣe ohun iyanu nla [awọn iṣẹ́ iyanu], ani ti o fi nmu iná sọkalẹ

lati ọrun wá si ilẹ aiye niwaju awọn enia. O si ntàn awọn ti ngbe ori ilẹ aiye jẹ

nipa awọn ohun iyanu ti a fi fun u lati ṣe niwaju ẹranko na; o nwi

fun awọn ti ngbe ori ilẹ aiye lati ya aworan fun ẹranko na ti o

ọgbẹ nipa idà, ti o si yè

(Ifihan :) A sì fi fun lati fi ẹmi fun àwòrán ẹranko naa; kí

o si maa sọrọ, kí ó sì mu kí á pa gbogbo awọn tí kò foribalẹ fun

àwòrán ẹranko náà.

Oluso-agutan Anderson: Ẹyin si wi pe, “Ki ni àwòrán ẹranko yii ti a fun ni

ẹmi? bí a se n sunmọ eyi, mo lérò pé a le è ni òye

erọ naa diẹ sii, nitori bẹẹ emi ko tilẹ mọ iru àwòrán ti eyi yoo

jẹ. Sugbọn o jẹ iru àwòrán ẹranko naa ti ó lè sọrọ,ti o si le mu

kí á pa awọn ti kò foribalẹ fun. Eyi si mu mi ranti Danẹili, orí

ikẹta, ẹ rántí Nebukadinẹseri ti o jọba lori ayé ti o laju nigba náà? Njẹ ẹ rántí

bi o ti se ère nla ti wọn si ni lati jọsin fun ère náà? Ati ohun ti yoo sẹlẹ

ti wọn kò bá jọsin fun ère náà? A pa wọn, abi bẹẹ kọ? njẹ eyi ko farapẹ irú eyi

ti a ri nibi yii? Eyi jẹ apẹrẹ asodi-si-Kristi. ẹ wo ẹsẹ . kókó rẹ niyi:

(Ifihan :-) O si mu gbogbo wọn,ati kékeré ati nla, ọlọrọ ati talaka, ominira

Ati ẹru,ki a fi àmì kan fun wọn ni ọwọ ọtun wọn, tabi ni iwaju wọn, ati ki ẹnikẹni

má le rà tabi ki o tà, bikose ẹnití ó bá ní àmì orukọ ẹranko na, tabi iye

orukọ rẹ. Nihin ni ọgbọn gbé wà. Ẹniti o ba ni òye, ki o siro iye ti mbẹ lara ẹranko naa:

nitori iye eniyan ni,iye rẹ na si jẹ ọtalelẹgbẹta o le mẹfa

Eyi jẹ ọkan ninu awọn ohun èlò ti Satani má n lo lati fi gbógun ti awọn onigbagbọ.

àmí ẹranko yii jẹ ohun èlò ti Satani n lò lati gbógun ti awọn ayanfẹ, nitori pe

tí ò kò bá lè rà tabi tà, o nira lati gbe ayé òde

òní, abi bẹẹko? Tabi ni ayé yoowu. nitoribẹ kì í se pé o se òfin ti o sọ pé bí o kò

jọsin fun asodi-si-Kristi ki a ó pa ọ nìkan. inúnibíni wà nibẹ pẹlu.

eyi jẹ gbígbé ogun ti awọn ayanfẹ. Ó tún mú ki o sòro fún awọn ayanfẹ lati rà

tabi tà nitori wọn ko ni àmì ẹranko naa, àmì ẹranko yii si ni

a o fun awọn ti o jọsin fun ẹranko náà nìkan. Awọn ti a ti gbala, awọn

ti o jẹ ayanfẹ, wọn ki yoo jọsin fun ẹranko náà. Bibeli salaye eyi daradara ninu iwe Mateu

ati níbòmíràn.nitoribẹ wọn ki yoo le rà tabi tà, wọn yoo si

fun awọn eniyan ni asẹ lati pa wọn. Nisinsinyi, wo ara rẹ gẹgẹ bi ẹni ti o wa ninu aye kan- n kò

sọ pe ilu kan tabi orilẹ-ede kan, Mo wi pe ninu AYE kan- tí o kò le rà

tabi tà ti a si tun fi asẹ fun awọn eniyan lati pa ọ. Njẹ o le ro

bi yoo se nira tó lati lè gbé ni iru ayé bẹẹ? Kì í se iyẹn nikan, kinni ka sọ

nipa awọn kamẹra asọniwo ti o n wọle? Kini ka sọ nipa awọn kamẹra ti n wo nọmba mọto?

kini ka sọ nipa awon ẹrọ ti n yẹ ara ẹni wo fínífíní? Tabi fífi káádì idanimọ rẹ hàn ni gbogbo ìkóríta ayẹwo? fífi

káádì idanimọ rẹ hàn kí o tó le wọ ọkọ oju-irin tabi ọkọ òfurufú? Njẹ o mọ eyi?

laipẹ iwọ yoo ni lati fi ohun miran han wọn. “Oya, jẹ ki a wo ọwọ ọtun rẹ

ọtun rẹ. O dara, máa lọ. kí ọjọ òní san ọ. Èyí kò jinna rárá. Bóyá

nígbà ti awọn eniyan ka èyí ní bi ọgọrun un ọdun sẹyin wọn kò wó lọna kanna

bí àwa se n wò ó. Nigba ti awa ba wò ó, ó da bi ẹni pe awọ kan boni loju, abi bẹẹkọ?

ìdí níyí ti mo se rò ó pe eyi le ti ku si dẹdẹ. Awọn Kristiẹni ode-oni ko mura silẹ fun eyi

rara. Wọn kò gbaradì fun eyi rara. Njẹ o mọ ohun ti o ni lati se? O ni lati murasilẹ

ninu ẹmi ki o si gbaradi ki o ma ba a di, “Kilo n sẹlẹ?” O

ní lati mura silẹ. O ní lati gbaradì. Idi niyi ti Ọlọrun se n kilọ fun wa

ti o si tun n kilọ fun wa. Idi niyi ti Pọọlu se n kilọ fun awọn eniyan to wa ni igba aye rẹ. O han gbangba pe wọn

kò gbé ni aye ipọnju nla naa, sugbọn wọn la

ipọnju ti wọn kọja bi gbogbo onigbagbọ se n là á kọja O wi pe, “ A kilọ fun yin. Nitootọ, nigba ti a

wà pẹlu yin, a sọ fun yin tẹlẹ awa yoo la ipọnju kọja bi o ti se waye yii,

bi ẹyin ti se mọ, nitori eyi ni a se nilo lati kilọ fun wa kí á sì ní òye pé eyi nbọ kí á lè

a le è kápá rẹ

Iran - Ikusidẹdẹ

Ronald Rasmussen: A kò kilọ fún àwọn Kristiẹni òde ìwòyí nípa àwọn isẹlẹ tí wọn yoo kojú

nínú ipọnju ńlá naa, dípò èyí, àwọn olusọ àgùntàn káàkiri ilẹ Amerika nkọ àwọn ènìyàn pé

ìgbásókè yoo sẹlẹ kí asòdìsí-Kristi tó gbé ogun rẹ ti àwọn àyànfẹ àti pé

ìgbásókè ni yoo jẹ isẹlẹ akọkọ nínú itolẹsẹẹsẹ àwọn asọtẹlẹ Ọlọrun. Ekọ yii,

ti a mọ si “ ikusidẹdẹ” n kọ ni pé Kristi le e padà wá ninu awọsanma nigbakugba àti pé

ki yoo si awọn ààmì bibọ rẹ. Bí ó ti wù kórí Bibeli nkọni pe bibọ Kristi

kì í se ní kiakia àti pé àwọn isẹlẹ miran wà tí o gbọdọ kọkọ sẹlẹ

Olusọ-agutan Anderson: O seése kí o ti gbọ ekọ yi ti o nsọ pe Jesu lè dé loni yii.

Taa ní o ti gbọ yen ri? ? A ń pè ní “ ikusidẹdẹ ìpadàbọ Kristi. Wọn gbagbọ pé

Jesu ń padà bọ nigbakugba. Mo ti béèrè lọwọ àwọn ènìyàn lọpọ ìgbà, nígbà tí wọn sọ fún mi

pé Jesu lè dé nígbàkugbà, " Níbo ni Bíbélì ti sọ èyí? " sùgbọn ohun tí wọn

kò lè fi saláì padà wà kòmí lòjù ni pé, " Bíbélì wí pé kò sì eni tì ó mọ ọjọ tàbí wákàtí

ti yoo wa." àti pé ọpọ ìgbà ni wọn kò le fi èyí hàn ọ sùgbón mo níló láti ràn wọn lọwọ

láti w aa. Sugbọn o wi pé, “Nkò ní aridaju yii. N kò mọ pàtó

orí Bibeli naa. Sugbọn mo mọ pe Jesu sọ pé kò si ẹni ti o mo ọjọ tabi wakati." Mo wi pé

"Jẹ ki n ràn o lọwọ. Ó sọ bẹẹ ninu Iwe Mateu :." Jẹ ki n kà á fun ọ ohun ti bibeli

sọ, nitori mo fẹ fi han ọ bi eyi ko se bá Bibeli mu nitori o jẹ aarin gbùn-gbùn ẹsin Kristiẹni

Tí o ba lọ si ilé ìtàwé Kristiẹni lọwọlọwọ bayii, wọn yoo ni orisirisi ìwé

ati awọn fidio, tani o ti gbọ nipa eré ori itage yii "Awọn To Kù Lẹyin"?. o jẹ itan arosọ patapata.

kò ni ohun kan se pelu Bibeli. Kò ba Bibeli mu rara. Bibeli si sọ ninu iwe Mateu ::

(Mateu :) Sugbọn ni ti ọjọ ati wakati náà, kò si ẹnikan ti o mọ ọ, rara, awọn angẹli ọrun kò tilẹ mọ ọ,

baba mi nikan

Olusọ-agutan Anderson: Awọn eniyan yoo tọka sí ẹsẹ Bibeli yii, wọn yoo sì wí pé "wo eyi? ko si ẹnikan

tí o mọ ọjọ tabi wakati naa. Eyi tumọ si pe o le sẹlẹ nigbakugba."Sugbọn ẹ kiyesi pe

o sọ pe "Sugbọn ni ti ọjọ naa ko si ẹnikan tí o mọ ọjọ tabi wakati ."Ibeere naa ni pé

“ọjọ wo?" ọjọ ti o sẹsẹ sọrọ tan nipa rẹ. oun niyi

ní ẹsẹ , O wi pe ọjọ náà nbọ lẹyin ipọnju naa. O sọ ninu ẹsẹ

ní kété lẹyin ipọnju awọn ọjọ naa ni òrùn yoo di òkùnkùn tí

osupa ki yoo fi imọlẹ rẹ han,awọn irawọ yoo jabọ lati oju ọrun, ti awọn agbara

tí o n be lọrun yoo sì mì tìtì

Olusọ-agutan Anderson: ó se apejuwe awọn isẹlẹ ti yoo sẹlẹ. Lẹyin eyi o wi pe:

(Mateu :) Sugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ ọ, rara, awọn angẹli ọrun kò tilẹ mọ ọ, bikose

baba mi nikan.

Olusọ-aguntan Anderson: nitoribẹ a kò mọ ọjọ tabi wakati na sugbọn ohun kan ti a mọ ni pé

yoo waye lẹyin ipọnju naa. Awọn eniyan ti o gbagbọ ninu igbasoke siwaju sáà ipọnju nla náà yoo se awọn

àforírò àràmàndà nibi tí iwọ yoo ti gbiyanju lati fi han wọn," ẹ wò ó, o sọ nibi yii pe LẸYIN

IPỌNJU NAA." Ohun ti wọn yoo sọ niyi, "eyi kì í se nipa igbasoke. Eyi

kì í se igbasoke." iwọ wi pe, " sugbọn bawo ni mo se mọ eyi? nitori pe yoo sẹlẹ leyin

ipọnju náà. Ati paapaa, a mọ wi pe igbasoke yoo sẹlẹ siwaju sáà ipọnju náà

Sugbọn nigba náà ni iwọ yoo beere lọwọ wọn, " Nibo ni Bibeli ti sọ pe igbasoke lè

sẹlẹ nigbakugba?" o sọ bẹ nibiyi, o wi pe ko si ẹnikan ti o mọ ọjọ tabi wakati náà"

"o sọ nisisiyi pe eyi ki i se nipa igbasoke" nigba ti o ba wi pe lẹyin igba ipọnju ni,

ajẹpe iwe Mateu kò sọ nipa igbasoke niyẹn. sugbọn nigba ti o wi pe ko si ẹnikan ti o mọ ọjọ tabi

wakati naa, nisisiyi lójijì ni Mateu tun bẹrẹ si ní sọ nipa igbasoke.Ati pe nígbà tí o ba sọ pe ẹni meji wa

ní oko,a mú ọkan a fi ekeji silẹ, eyi tún tumọ si igbasoke. " sa

pa ẹnu mọ kí o si se ohun ti wọn wi fun ọ.sá pa ẹnu mọ ki o si gbagbọ ninu igbasoke siwaju saa ipọnju náà nitoripe

mo wí bẹ." iwọ wi pe, " salaye lọna mejeeji je olootọ, salaye lọna mejeeji." O dara, eyi ni

ọna keji. Pa ẹnu mọ ki o si gba ohun ti mo ni ki o so gbọ ki o si dẹkun ibeere.

pa ẹnu mọ ki o si gbagbọ nitori pe mo sọ bẹ. Eyi jẹ abala igbasoke siwaju sáà ipọnju. otitọ ni. wọn

kò ní ohunkóhun. Emi ní ọpọlọpọ ẹsẹ bibeli, sugbọn wọn

kò ní ohunkóhun. Bí ó ti wù kí ó rí awọn ekọ òdì míràn má n dá lórí awọn ẹsẹ bibeli kọọkan

ti a yí sihin-sọhun ,awọn eniyan yóò yọ ẹsẹ bibeli kan jade wọn yóò dori rẹ kodo

wọn a sí yii sihin-sọhun. Ekọ igbasoke siwaju ipọnju naa kì í se ẹsẹ bibeli ti a n yí sihin-sọhun. wọn kò

ní ẹsẹ bibeli rara ni. Kò sí ẹsẹ bibeli tí o sọ ohunkohun nipa pe igbasoke yóò

waye kí sáà ipọnju na to de. Ó jẹ ẹkọ kan ti ko ba bibeli mu

rara. Ó da lori isẹse. ó da lori iwe tabi aworan asàpèjùwe kan ti ẹnikan kà.

kò dá lori bibeli. kò wá lati inu bibeli. kò fi

ẹsẹ mulẹ ninu bibeli. Mo ri wi pe igbakugba ti mo ba se alaye yìí fun awọn eniyan ti o wà ninu ijọ

kì í sòro fun wọn lati ni òye ẹkọ yii. Awọn ti o wa lori aga iwaasu ni kì í

gba ẹkọ yii gbọ, èmi yoo si sọ idi rẹ. ẹkọ igbasoke siwaju ipọnju naa ni o jẹ gbajúgbajà ẹkọ

tí o ba fẹ di ilumọka, o ní lati waasu nipa igbasoke siwaju sáà ipọnju naa. Sugbọn ti o ba bẹrẹ sí ní

waasu pe igbasoke yoo waye lẹyin sáà ipọnju naa, won yoo dẹyẹ si ọ

wọn yoo yọ ọ kuro lẹgbẹ, wọn yoo si kọ ọ ni ile ijọsin,nitoripe

wọn kò fẹ iyipada lori ẹkọ yii. nitori awọn eniyan kan wa lóde ti wọn ní

ètò lati ri wi pe ẹnikankan kò gbọ otitọ lori ẹkọ yi. otitọ ni.

ọna ti wọn n lo lati fi ẹkọ yii sinu okunkun ni nipa ibẹru ati ìdáyàjani. Mo má n ba

ba awọn olusọ-agutan sọrọ lori eyi lọpọ ìgbà. Mo ma n fi otitọ han wọn lori eyi.wọn gbagbọ pelu mi. sugbọn wọn

kì í kọ ẹkọ yii lori aga iwasu wọn, nitori wọn bẹru ki gbogbo awọn

ọrẹ wọn to jẹ olusọ-agutan ma kọ ẹyin si wọn. wọn ko ni le ni itakurọsọ lori eyi.

wọn ko ni le waasu ninu awọn ijọ wọnyi nitoripe o gbọdọ je ẹni ti o

gbagbọ ninu igbasoke siwaju saa ipọnju náà ki o to le ba wọn kẹgbẹ pọ. Sugbọn ti o ko ba gbagbọ ninu eyi,o kò sí ninu agbo won. ọpọ

ìgbà ni wọn ki yoo gbà nitori wọn ko fẹ jẹ majele ati pe wọn ti

se iwaasu ti o lòdì lati ọpọ ọdun sẹyin. Wọn kò fẹ gba eyi gbọ. wọn kò fẹ

gbà pe ẹkọ òdì ni ile ẹkọ bibeli wọn kọ wọn. wọn kò fẹ gba pe wọn

se àsìse. Gbogbo eniyan lo ma n se àsìse. Sugbọn a ma n dagba sii. A sì ma n kọ ẹkọ titun.Tí o ba

se àsìse lori ohun kan, o ni lati se atunse lori rẹ. Bibeli sọ ni nu iwe Galatia ::

(Galatia :) Njẹ nisisiyi eniyan ni emi nyi lọkan pada tabi Ọlọrun? tabi eniyan ni emi nfẹ lati wu? nitoripe bi emi

ba si nwu eniyan, emi ki yoo le se iransẹ Kristi

Olusọ-agutan Anderson: Awọn oniwaasu yii ni lati pinnu boya wiwu eniyan lo se pataki jù, nipa

wiwaasu ohun to jẹ gbajugbaja,wiwaasu nipa igbasoke siwaju sáà iponju naa nitoripe ohun ni gbogbo eniyan

fẹ gbọ, nitoripe wọn fẹran ere ori itage ati erọ àmúseré fidio pelu erọ àmúseré ori pátákó

ati erọ DVD. tabi ki wọn ki o tẹle ohun ti bibeli sọ ni pàtó ki wọn si dide lati waasu pe

igbasoke yoo waye lẹyin sáà ipọnju naa. Eyi jẹ apẹrẹ pataki awọn to gbe ohun ti eniyan

sọ lékè ohun ti Ọlọrun sọ. Ó jẹ apẹrẹ pataki ailo bibeli gẹgẹ bi

alasẹ tó gaju ati titẹle àsà,titẹle ohun ti wọn kọ wa, titẹle

ohun ti awọn eniyan nsọ, titẹle ohun ti n sẹlẹ laye dípò ka tẹle ohun ti bibeli sọ.

Olusọ-agutan Jimenez: Ní ìgbà kan rí mo gbagbọ ninu igbasoke siwaju sáà ipọnju naa o jẹ ohun ti a kọ mi lati ìgbà ti mo

wà ni ọmọde, ako si le jiyan ohun ti wọn ba sọ fun wa sugbọn ni ìgbà ti a mu mi mọ

otitọ, ti mo si bẹrẹ si ni ka bibeli ati ohun ti bibeli kọ ni pato, mo ni lati

se ìpinnu fun ara mi boya maa tẹle ohun ti aye tẹle, boya

maa tẹle ohun ti gbogbo aye tẹle, tabi, ki n mu iduro mi ninu ohun ti mo gbagbọ

tí mo si mọ pe o je otitọ. Ninu igbesi aye mi mo ti ni adojukọ

nipa pe awọn eniyan n sọ ọrọ buburu nipa mi nitori iduro mi ninu igbasoke siwaju sáà iponju náà

sugbọn mo ni ireti pe boya o n gbọ eyi tabi ò n wò ó, tabi o ti bẹrẹ

sí ní rí otitọ nipa eyi, pe iwọ yoo fi igbagbọ jade ti iwọ yoo

duro lati ran wa lọwọ lati koju ìjà si ẹkọ ti ko ba bibeli mu yii

eyi ti n se ẹkọ igbasoke siwaju sáà ipọnju naa.

Ẹsẹ bibeli miran ti o mu mi gbagbọ ni iwe Tẹsalonika keji,ori keji, ẹsẹ ikini si

ẹsẹ kẹta

( Thessalonians :-) Sugbọn awa mbẹ yin ara, nitori ti wiwa Jesu Kristi Oluwa wa

[ó n sọ nipa pe Jesu Kristi n bọ], ati nipa

ipejọpọ wa sọdọ rẹ [eyi ti o tọka si igbasoke] ki ọkan yin ki o ma se tètè mì

tabi ki ẹ mase jáyà, yálà nipa ẹmi,tabi nipa ọrọ, tabi nipa iwe bíi lati ọdọ wa wá,bi ẹnipe

ọjọ oluwa de. [ó tún sọ nipa igbasoke lẹẹkansi]

Olusọ-agutan Jimenez: ó wi pe," ẹ wò ó, kò kù si dẹdẹ. kì í se isẹlẹ ti o kàn ti

yoo sẹlẹ." ó wi pe," Ẹ mase jẹ ki ẹnikẹni tan yin jẹ lọnakọna nitoripe ọjọ náà (o n sọ

nipa ọjọ náà tí a ó wà ni ipejọpọ) kì yoo de bikosepe ìyapa nì

bà kọ de ki a si fi ẹni ẹsẹ nì han, tí í se ọmọ ègbé". A ti fi idi rẹ mulẹ nibiyi

ninu bibeli wi pe ọjọ ipejọpọ wa pẹlu Jesu Kristi Oluwa wa ki yoo

bikosepe ìyapa nì bà kọ de ki a si fi ẹni ẹsẹ nì han.ohun kan soso

tí ó kù si dẹdẹ ni bibọ Asodi-si-Kristi

Olusọ-agutan Anderson: Bibeli sọ fun wa ni pàtó pe ọjọ Kristi kò tí ì sun mọ etílé

o wi pe bi ẹnikẹni ba gbiyanju lati sọ fun yin pe ọjọ Kristi kù si dẹdẹ, ẹni náà

n parọ tàn yin jẹ ni. Ẹni náà jẹ ẹlẹtan. o wi pe ẹ ma se jẹ ki a tan yi jẹ nipa ọrọ tabi

ẹmi tabi iwe lati ọwọ wa, iwe ti o wa lati ọdọ wa to wi pe

ọjọ bibọ Kristi kù si dẹdẹ. Ẹ ma se jẹ ki ẹnikẹni tàn yin jẹ lọnakọna. Ọjọ náà ki yoo wá bikosepe

awọn ohun kan kọkọ sẹlẹ. igbasoke ko le waye nigbakugba. ipọnju náà

kọkọ gbọdọ waye ná. Asodi-si-Kristi gbọdọ kọkọ gba ijọba ná. Òrùn ati Òsùpá yoo

dí okunkun kí ọjọ nla ati ọjọ ẹru Oluwa to de. Bibeli

sàlàyé rẹ daradara. Ọjọ naa ki yoo wá bikosepe ìyapa nì ba kọ de ki a si fi ẹni

ẹsẹ ni han. A o fi asodi-si-Kristi hàn. Asodi-si-Kristi yoo joko ninu tempili

Ọlọrun yoo si pe ara rẹ ni Ọlọrun. Asodi-si-Kristi yoo wà ni ijọba ki igbasoke

tó sẹlẹ.Eyi kò le rárá. Sugbọn ti a ba wo iwe Luku , o waye ní sisẹntẹle

siwaju Mateu , nitoripe Mateu ati Luku farapẹra. Nitoribẹ ninu Luku

a kà nipa isẹlẹ akosilẹ akọkọ ti Jesu ti n kọ awọn ọmọ eyin rẹ ni

ẹkọ yii. Bibeli wi pe:

(Luku :) Bí ó ti rí ní ọjọ Noa, bẹni yoo ri ni ọjọ

ọmọ-eniyan [Jesu Kristi]

Olusọ-agutan Anderson: Ọpọ eniyan ni yoo tumọ eyi sí pé awọn eniyan

di ẹni buburu bí ti ọjọ Noa. Pẹlupẹlu, O sọ pe bí ó ti rí

nigba aye Lọti, bẹẹni yoo rí ní ọjọ bibọ ọmọ eniyan.

awọn eniyan yoo si wi pe "bẹẹni, yoo buru gẹgẹ bí ó ti rí ní Sodomu ati Gomora."

wọn yoo si tọka si awọn ohun tí ó n sẹlẹ lawujo wa gẹgẹ bi

irú eyi tí ó sẹlẹ ni Sodomu ati Gomora. wọn yoo si wipe o buru gẹgẹ bi

bí ó ti rí ní Sodomu ati Gomora tabi ki wọn wipe yoo buru bí ó ti rí ní ìgbà aye Noa

Sugbọn nitootọ, eyi kì í se àfiwé ti Jesu n se.

Olusọ-agutan Jimenez:ní ẹsẹ o wi pe:

(Luku :-) Gẹgẹ bí ó ti rí ní ọjọ Lọti, wọn njẹ,wọn nmu,

wọn nrà, wọn ntà, wọn ngbìn, wọn nkọle; sugbọn ni ọjọ na ti Lọti jade kuro

ni Sodomu, òjò iná ati sulfuru rọ lati ọrun wa, o si run gbogbo wọn

Olusọ-agutan Jimenez: ohun tí a rí kọ ninu ayọka bibeli yi ni pé nigbati a mu Lọti jade

ni Sodomu, eyi se apẹrẹ Igbasoke. A ri angẹli meji nlọ si Sodomu ti

o n sapẹrẹ ayé ti wọn si mú awọn onigbagbọ jade kí á tó tú ibinu Ọlọrun

sori ilu naa. Iwe Ifihan kọ wa ni ohun kan naa. Bibeli sọ ninu iwe

ifihan pe Jesu Kristi rán awọn angẹli rẹ lati kó awọn ayanfẹ jọ ati lati mu wọn jade

kuro ninu ayé. Iwe ifihan sọ fun wa ni pato pé aabọ wakati kọja

lọ,lẹyin eyi ni o bẹrẹ si ni tú ibinnu rẹ jade.

Scene - Apejuwe Igbasoke

Olusọ-agutan Anderson: Awose "awọn ti o ku sẹyin" yii ninu eyi ti gbogbo eniyan pòóra ti gbogbo eniyan si

si n sọ pe, " nibo ni gbogbo wọn lo?" Eyi kì í se ohun ti awọn eniyan yoo ma wi. Nitori

Bibeli nsọ pé ní ọjọ kan naa tí a ó gbà wá, Ọlọrun yoo bẹrẹ sí í

rọ̀jò idajọ. Ọlọrun yoo bẹrẹ sí í rọjo iná ati imí-ọjọ́ sori aye yii. Awọn eniyan

yoo bẹrẹ sí í mọ̀ pé nnkan kan nṣẹlẹ. Awọn eniyan yoo maa sá àsálà.

Awọn eniyan yoo bẹrẹ sí í sọ fun awọn oke pé kí ó ṣubu lù wọ́n ki ó sì daabo bò wọn nitori

iná, imí-ọjọ́, ibinu naa tí yoo wá. Ọjọ kan naa tí a bá gbà wá

kuro nihin ni ọjọ kan naa tí Ọlọrun yoo bẹrẹ sí í rọ̀jò ibinu rẹ̀. Idi niyẹn

tí ó fi jẹ́ pé nigba tí oorun ati oṣupa bá ṣookun bibeli nsọ pé ọjọ nlá ibinu oun ti dé

tani yoo sì lè duro? Nitori pé ọjọ kan naa yẹn, ọgbọn iṣẹju lẹyin rẹ̀, Ọlọrun nbẹrẹ sí í rọ̀jò

iná ati imí-ọjọ́. Nitori naa ní ori kẹfa iwe Ifihan, oorun ati oṣupa ṣookun. Ori ikeje,

ogunlọgọ awọn onigbagbọ nfi ara hàn ni ọrun. Ori ikẹjọ, ó nbẹrẹ sí í rọ̀jò

ibinu rẹ̀. Ó jẹ́ ohun ti Bibeli nkọni ninu iwe Matteu ori ikẹrinlelogun gan an. Oorun ati oṣupa ṣookun, lẹyin naa

igbasoke. Ó rọrun tó bẹyẹn. Mo maa nbá awọn eniyan tí ó gbagbọ ninu igbasoke tí ó ṣaaju ipọnju sọrọ

wọn yoo sì maa sọ fun nnkan kan fun mi ninu meji ni gbogbo igba. Boya wọn yoo sọ fun mi pé

a kò tilẹ mẹnuba igbasoke ninu Iwe Ifihan tí ó jẹ́ ohun tí ó ṣajeji pupọ

lati sọ niwọn igba tí ó jẹ́ pé iwe Ifihan nṣalaye ni kikun tó bẹẹ nipa awọn iṣẹlẹ igba

ikẹyin. Lati yọ irú iṣẹlẹ tí ó ṣe pataki tó bẹẹ bí bibọ̀ Jesu Kristi ninu awọsanma ati gbogbo

onigbagbọ lati atẹyinwa tí a ngba soke pẹlu rẹ̀ ní awọsanma...iyẹn

jẹ́ irú iṣẹlẹ pataki tó bẹẹ. Lati sọ pé a kò mẹnuba á rara ninu iwe Ifihan,

pé kì í ṣẹlẹ rara ninu iwe Ifihan, kò ṣe é finu rò. Ṣugbọn nitori

pé ó tabuku nnkan tó bẹẹ lati sọ pé a kò rí igbasoke ninu iwe Ifihan rara

ọpọlọpọ awọn eniyan tí ó ṣaaju ipọnju ti gbiyanju lati wá a kí wọ́n sì lè rí nnkan kan tí wọ́n lè

lò gẹgẹ bi igbasoke tí ó ṣaaju ipọnju, ohun tí mo sì ngbọ nigba gbogbo niyi

lera-lera – Ifihan :. Ifihan ori kẹrin, ẹsẹ ikinni wipé:

(Ifihan :) Lẹhin nkan wọnyi emi wo, si kiyesi i, ilẹkun kan sí silẹ li ọrun: ohùn kini

ti mo gbọ bi ohùn ipè ti mba mi sọrọ, ti o wipe, Goke

wa ihin, emi o si fi ohun ti yio hù lẹhin-ọla hàn ọ.

Oluṣọ-agutan Anderson: Nitori naa eyi jẹ́ ohun kan bí ipè. Kò sí ipè ninu ẹsẹ yii

tí ó nsọrọ tí ó sì nsọ fun Johannu (ẹyọ kan, eniyan kan), “Goke wa ihin, emi o si

fi ohun ti yio hù lẹhin-ọla hàn Ọ.” Wọn yoo sì wipe, “Wò ó, igbasoke niyẹn

tí ó wà nibẹ gan an.” A ngba ọkunrin kan soke. wọn yoo sọ pe igbasoke niyẹn. Ohun tí ó tabuku ẹni

nipa eyi ni pé wọn kìí tilẹ kà ẹsẹ keji. Nitori pé ní ẹsẹ keji o nsọ pé:

(Ifihan :) Lojukanna mo si wà ninu Ẹmí, si kiyesi i, a tẹ́ itẹ́ kan

li ọrun, ẹnikan si joko lori itẹ́ na.

Oluṣọ-agutan Anderson: Igbasoke kì í ṣe ẹmi tí ó ngoke lọ sí ọrun. Igbasoke jẹ́

ajinde ara. A ó gbà wá soke lojukooju sí ofurufu. Eyi kì íkàn íṣe

irú nnkan kan nibi tí ẹmi wa ti ngoke lọ. Bibeli yè kooro pé igbasoke jẹ nnkan,

afojuri ti ajinde awọn oku ninu Kristi tí yoo kọ́kọ́ jinde. awa tí a wà laaye

tí a ṣẹku ni a ó gbà soke pẹlu rẹ̀ ninu ara. Nitori naa igbasoke ti ẹmi yii

fun ẹnikan, iyẹn Johannu, dajudaju kì í ṣe igbasoke naa. Tí ẹ bá sì rò pé eyi ni

igbasoke naa, nṣe ni ẹ nsọ itumọ tí ó mẹ́hẹ jọjọ. Ó pani lẹrin nitori pé awọn eniyan

tí mo bá sọrọ tí wọ́n gbagbọ ninu igbasoke ṣaaju ipọnju nsọ pé awọn ntumọ Bibeli ní ọna taara.

sibẹ nigba tí ẹ bá beere lọwọ wọn pé kí wọ́n fi igbasoke hàn yin ninu iwe Ifihan, wọn yoo mú yin lọ sinu iwe Ifihan

Ori ikẹrin, ẹsẹ ikini. A ngba ọkunrin kan soke sí ọrun. Wọn kò tilẹ nkà á dé ẹsẹ ikeji nigba tí ó nwipe,

“Lojukanna mo si wà ninu Ẹmí: si kiyesi i, a tẹ́ itẹ́ kan li ọrun." Kò

tilẹ goke lọ ninu ara. Àgọ́-ara rẹ̀ ṣì wà nibẹ ni Erekusu Patimo. awọn oku ninu Kristi

ni yoo kọkọ jinde. Lẹyin naa ni a ó gbà awa tí a wà laayè tí a sì ṣẹ́kù soke pẹlu

wọn ní awọsanma. Eyi kì íkàn íṣe irú iṣẹlẹ ti ẹmi kan. Eyi jẹ́

iṣẹlẹ afojuri. Iyẹn jẹ́ ifẹloju gidi lati sọ pé i gbasoke niyẹn. Awọn tí

ó gbagbọ ninu igbasoke ṣaaju ipọnju ní lati sọ pé iwe Ifihan, ori kẹrin, ẹsẹ ikini ni igbasoke naa

nitori pé iyẹn nikan ṣoṣo ni wọn kò tilẹ lè rí ninu iwe Ifihan ṣaaju

ipọnju naa. Kò kàn sá bá a mu. Mo lero pé, wọ́n ní lati wá nnkan kan. Mo gbọ́njú

bá ikọni nipa igbasoke tí ó ṣaaju ipọnju ni. Nigba tí mo wà léwe, a kọ́ mi pé a

kò mẹnuba á rara ninu iwe Ifihan. Gbogbo igba ni mo nronú pé nnkan kan wà nibẹ tí ó mú ifura wá

nipa iyẹn. Iṣẹlẹ tí ó ṣe pataki tí ó sì jọjú bí igbasoke...Ẹ ti ní iwe kan nipa

asọtẹlẹ igba ikẹyin, iyẹn iwe Ifihan, kì ísì íṣe pé ó mẹnuba á? Kì í

mọgbọn wá rara. Gbogbo igba ni nkọ́ mi gẹgẹ bi èwe pé igbasoke naa yoo wà nibi tí ẹ sá ti

ngbé igbe-ayé yin lọ tí ó sì jẹ́ pé lojiji ẹ poora. Ṣugbọn ó pọ̀ pupọ jùgoing about your life and all of a sudden you just disappear. But it’s so much greater

jù iyẹn lọ, nitori pé bibeli nsọ pé gbogbo oju ni yoo rí i. A ó rí oorun

ati oṣupa tí ó ṣookun. Ó nsọ ninu iwe Luuku, ori ikọkanlelogun pé nigba ti ẹ bá nrí awọn nnkan yii tí ó

nwá sí imuṣẹ, ó nsọ pé ẹ wòkè, nitori pe irapada yin ti sunmọ etile. Ẹ fi inu rò ohun ti yoo

jọ ni saa yẹn nigba tí oorun bá ṣookun, oṣupa ṣookun, awọn irawọ bẹrẹ sí í jabọ,

a sì wòkè tí a sì nmọ̀ pé oun ni. Ó wà nihin. A ti ṣe é yọri.

Kent Hovind: Ó fẹ́ fi ara jọ sinima ṣíṣe. Njẹ́ ẹ ti wo awọn eniyan olokiki

kí wọ́n wá sí ibi kan. Gbogbo igba ni wọn maa nni itanṣan imọlẹ ati didun ibọn ati

èéfín ati gbogbo nnkan miran. Wọ́n fẹ́ mú ori eniyan wù. “Ẹ gbọ́, ẹ wò mí." Tí

ẹ bá nkà iwe ifihan, ori ikẹfa abi Matteu, ori ikẹrinlelogun, Maaku, ori ikẹtala, abi Luuku, ori ikọkanlelogun, eyikeyii ninu ibi awọn ibi kika naa tí ó

njuwe oorun ati oṣupa tí ó nṣookun, ó njọni lójú pupọ nigba tí ẹ bá wò ó. Oorun

ati oṣupa ṣookun eyi tí yoo sá fẹ́rẹ̀ ẹ́ pè akiyesi gbogbo eniyan lori ilẹ aye.

Ṣugbọn ó tún nsọ pé ilẹ-ríri kan wà, nitori naa tí ẹ bá jẹ́ afọju, yoo ṣì

pè akiyesi yin.

Oluṣọ-agutan Anderson: Nigba naa ni ó sì jẹ pé ní saa okunkun biribiri yẹn, Jesu Kristi mbọ ní

awọsanma, tí ó ntan imọlẹ sí gbogbo oju ofurufu bí manamana

nibi tì ó ti ntan imọlẹ lati ìkangun ọrun kan dé ekeji, a ó sì woke tí a ó sì rí

Jesu Kristi tí ó mbọ Jesus ninu awọsanma. A ó mọ nigbakigba tí a bá ti fẹ́ gba wá

soke pẹlu rẹ̀. Mo ni ireti pé ng ó wà laaye lati ri ọjọ yẹn. Mi ò ng ò mọ̀ boya eyi yoo

ṣẹlẹ loju ẹmi wa. Mo ní ireti pé eyi yoo ṣẹlẹ loju ẹmi mi. Mo ni ireti pé ng ó lè fi ara dà

inunibini ati ipọnju yẹn. Irú ohun ẹru wo ni yoo jẹ́ lati wà laye ní

ọjọ yẹn nigba tí Jesu Kristi mbọwa ninu awọsanma. Ó ga pupọ jù bí a ti mú wa

gbagbọ lọ.

Kent Hovind: Ero pé ipadabọ lẹẹkeji ìdákọ́nkọ́ yoo wà nibi tí awọn eniyan

ti ní lati wadii ohun tí ó ṣẹlẹ nikẹhin kò kàn jẹ́ otitọ rara. Gbogbo eniyan ni yoo

kiyesi i pẹlu ìṣíde alárinrin yii.

Oluṣọ-agutan Anderson: Ootọ gan an ni ẹ sọ. Ninu iwe Ifihan, Ori ikinni, ó wipe "Kiyesi i, o

mbọ̀ ninu awọsanma; gbogbo oju ni yio si ri i. "Ẹ kiyesi i pé "mbọ̀" jẹ nnkan tí ó

nṣẹlẹ lọwọ lọwọ. Iyen ni igba tí ó bá tún wá. Ó mbọ̀ ninu awọsanma gbogbo oju ni yoo sì rí

i. Ó yéni yekeyeke. Sí awọn tí a kò gbala eyi yoo ṣẹru bawọn doju ikú. Bibeli

wipe nigba tí wọ́n bá rí i tí ó mbọ̀ ninu awọsanma, wọn yoo maa pohun rere ẹkun, wọn yoo

maa sọkun, ẹru yoo bà wọ́n doju iku. Ṣugbọn fun awa tí

a nwọna fun ifarahan rẹ̀, ara wa yoo yá gágá, inu wa yoo dun, yoo

sì jẹ́ imọlara iyanu lati mọ̀ pé oun niyi.

Abala Ikẹtala - Ìkádìí

Oluṣọ-agutan Jimenez: emi funra mi nfẹ́ kí fanran yii yọri sí rere. Ng ó fẹ́ kí fanran yii

lè wulo fun Ọlọrun lati là oju awọn eniyan sí otitọ. Mo kàn lero pé ó

ṣe pataki tó bẹẹ tí a bá lè pada sinu Bibeli. mo ranti nigba tí mo wà ní ọ̀dọ́ langba tí mo sì

ndagba, mi ò tilẹ̀ fẹran lati maa kà iwe Ifihan nitori pé mo kàn sá rò pé

Kò lè yé mi abi pé gbogbo igba tí mo bá ti nkà nnkan kan, mo maa nbeere boya,

“Ṣé nitootọ ni ó sọ bẹyẹn? Ṣé nitootọ itumọ rẹ̀ niyẹn?” nigba tí mo lè kẹkọ̀ọ́ nipa

otitọ nipa igbasoke, nṣe ni ó kàn ṣí iwe mimọ silẹ fun mi. Mo nifẹ̀ẹ́ lati maa kà iwe

Ifihan nisisiyi. Bi mo ti nlọ ninu rẹ̀, ó kàn sá nmu ọgbọn wá tó bẹẹ. mo sá lero pe

tí a bá lè kàn sí ẹgbẹ Kristiani nibẹ yẹn, sí ẹgbẹ alakatakiti ẹsìn,

sí ẹgbẹ Onitẹbọmi nibẹ yẹn, tí a sì lè là oju wọn sí ọ̀ràn yii, a jẹ́ wipe

boya yoo mú ifẹ ọrọ Ọlọrun wá ati isọji ọrọ Ọlọrun ati

iṣoji kíkọ́ ọrọ Ọlọrun pada sori awọn aga iwaasu orilẹ-ede wa, nitootọ a sì lère

rí i kí iṣẹ́ nla di ṣíṣe fun Ọlọrun.

Oluṣọ-agutan Anderson: Idi tí a fi ṣe fanran yii kì íṣe lati ṣe aṣelékè abi lati

sá tọ́ka sí aṣìṣe ẹnikan tí ero rẹ̀ nipa asọtẹlẹ Bibeli yatọ diẹ sí tiwa. Iyẹn

kọ́ ni koko naa. Awọn iṣẹlẹ yii jẹ́ iṣẹlẹ otitọ tí yoo waye. bibeli nsọ fun wa pé

ijọba agbaye kan ṣoṣo YOO wà. Ẹsìn agbaye kan ṣoṣo YOO wà. Owó ìna kan ṣoṣo

fun gbogbo agbaye yoo wa. Eyi kì íṣe ero ọtẹ lasan tí awọn eniyan lè fi ọwọ rọ́ sẹyin. Awọn iṣẹlẹ yii

yoo ṣẹlẹ nitootọ. A ó pa awọn eniyan. A ó pa awọn eniyan ní yanturu. Ìyan yoo

wà. Ajakalẹ arun yoo wà. Inunibini yoo wa. Yoo

yatọ sí ohun yoowu ti aye yii ti là kọja rí tí ó sì jẹ́ pé awọn Kristiani kò

mura silẹ fun u rara. Nitori pe wọn ti gbagbọ ninu itan àtọwọ́-dọ́wọ́ ti igbasoke

tí ó ṣaaju ipọnju. Mo gbagbọ ninu igbasoke. Ikọni Bibeli ni. Ṣugbọn igbasoke nwaye

LẸYIN ipọnju.

Oluṣọ-agutan Jimenez: Ẹ nsọ pé, “Oluṣọ-agutan Jimenez, kí ló dé tí eyi fi ṣe pataki?” Idi tí ó fi ṣe pataki niyi.

Igbasoke tí ó ṣaaju ipọnju jẹ́ ikọni tí mo gbagbọ pé kò fi bẹẹ ṣe pataki

nipa ohun tí a ṣe. Nitori pé ohun yoowu kí ó jẹ́, boya mo maa fi ọwọ rọrí kú gẹgẹ bí arugbo

abi ng ó kàn là aye kọja, tí ng ó maa lò awọn aaye isinmi mi, tí ng ó maa dokowo ninu owó mi,

tí ng ó maa gbadun, tí ó sì di ọjọ kan tí ng ó kàn poora, kí nnkan buburu yoowu tó ṣẹlẹ.

Ikọni tí a nkọ́ ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan ni mo gbagbọ pé ó jẹ́ kí á ti

ya ọlẹ pupọ tí a si ní itẹlọrun pupọ ninu ẹsìn kristiẹni wa. A ní lati kede ihinrere. a ni lati jade

sita nibẹ yẹn. A ni lati kọ́ awọn eniyan lẹkọọ kí a sì sọ fun wọn pé, Ẹ wò ó, inunibini mbọ̀.

Ẹ lọ sí aaye isinmi ranpẹ yin kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí ẹ fẹ́ ṣe, ṣugbọn ó sàn

kí ẹ fun ọkunrin ti inú yín lókun. Ó sàn kí ẹ mú Bibeli yin wọle. Ó sàn kí ẹ bẹrẹ sí í kẹkọọ

nipa Bibeli. Ó sàn kí ẹ bẹrẹ sí í bá Ọlọrun rin kí ẹ sì mọ̀ Ọlọrun. Ó sàn kí ẹ bẹrẹ sí í kà

Bibeli. nitori pé ọjọ kan lè wà nigba tí wọn yoo mú Bibeli yii kuro lọdọ yin," Lonii a

fun wa ní ẹkunrẹrẹ ominira lati pejọ pọ̀, lati ṣí Bibeli, lati waasu ọrọ naa, ṣugbọn

ọjọ kan lè dé tí ikórajọpọ yii yoo lodi sí ofin, nigba ti Bibeli yii yoo

lodi sí ofin, nigba ti ohun tí a nṣe nisisiyi yoo lodi si ofin. Tí a ó bá ní ọkàn

fun Ọlọrun, a ó gbé ihinrere Jesu Kristi tọ̀ awọn eniyan lọ.

Oluṣọ-agutan Anderson: Gbogbo iyẹn lati sọ eyi. awọn nnkan tí mo ti waasu rẹ̀ fun yin yii lè ti

má ti bí yin ninu. Nigba tí inunibini bá dé, nigba tí a bá ní kí ẹ gba ami ẹranko naa

sí ọwọ ọtun yin abí iwaju ori yin, ẹ ó ranti iwaasu yii. Boya kò ní í ṣẹlẹ

loju ẹmi wa, boya yoo ṣẹlẹ.ṣugbọn tí ó bá rí bẹẹ, ẹ ó ranti iwaasu yii. Iyẹn

ni idí ti Jesu fi sọ ọ́ idí sì niyẹn tí mo fi nsọ ọ́. Ẹ nṣo pé, "Ṣé eyi wà lati dayafo wá ni?" Rara,

Bibeli nsọ pé ninu aye ẹ ó ní ipọnju. Ẹru bà yin nipa rẹ̀? Rara. Ó sọ

pé ninu aye ẹ ó ní ipọnju, ṣugbọn ẹ tujuka, "Mo ti ṣẹgun aye."

Ẹ tujuka. Ẹ maṣe daamu. Ẹ maṣe binu jade kuro nibi iwaasu naa pe, "Ọkunrin yii, ṣé ara rẹ dá?

Orí bibẹ? Tuubu? Iyàn? Ajakalẹ arun? Ṣé ara rẹ dá?" Rara, ẹ tujuka. Ó

ti bori aye. Boya yoo ṣẹlẹ loju ẹmi wa, boya kò ní ṣẹlẹ, Ṣugbọn eyi o

wù kí ó jẹ́, bí Ọlọrun bá wà fun wa, tani ó lè kọju ija sí wa? Ẹ yin Jesu Kristi. Ẹ jẹ́ kí á tẹ̀ orí wa ba

kí a sì gbadura. Baba, a dupẹ́ lọwọ rẹ tó bẹẹ fun otitọ tí ó yè kooro ninu ọrọ rẹ

a sì dupẹ lọwọ rẹ tó bẹẹ fun fifun wa ni Ẹmi Mimọ rẹ lati tọ́ wa. mbá má ti

lè fi inu rò nnkan yii funra mi pẹlu gbogbo igbọ́kúgbọ́ tí mo ngbọ lati ọdọ awọn eniyan yii

tí wọn nparọ́ fun emi ati Scofield, ṣugbọn a dupẹ lọwọ rẹ fun Ẹmi Mimọ pé ninu yará yẹn fun ọpọlọpọ

ọdun ni wọ́n fi nla gbogbo iyẹn kọja tí wọ́n sì nfi koko ọrọ mẹta yii sinu ọkàn mi. Awọn koko ọrọ

ọrọ tí ó ṣẹse wọnu ọkan mi lati inu iwe Matteu ori gẹgẹ bí ọdọmọkunrin ọdun mejila ni: LẸ́YÌN ÌPỌ́NJÚ NÁÀ.

Mo gbà á ladura pé awọn koko ọrọ yẹn yoo wọle sinu ọkàn àti ọpọlọ ẹnikọọkan tí ó wà nihin

ní àṣálẹ́ yii. A nifẹẹ yin a sì dupẹ lọwọ yin ní orukọ Jesu ni a sì gbadura, amin. Ẹ jẹ́ kí a kọrin

ranpẹ́ kan kí a tó maa lọ.

-

ORIN: Ó Dara Fun Ọkàn Mi

Oluṣọ-agutan Jimenez: Aayo orin mi niyi a ó sì kọ aayo ẹsẹ mi

nisisiyi. Ọpọlọpọ igba tí ẹ bá nkọ awọn orin, nṣe ni ẹ kàn nbẹrẹ orin. Ẹ kì í

ronu nipa awọn ọrọ naa ati ohun tí ó nsọ. Ẹ wò ẹsẹ ikẹta orin yii.

Ó nsọ pé, “Ẹṣẹ mi, ah, ayọ pipé ti ironu ologo." Ẹ nsọ pé, "Ó dara, kínni

ayọ pipé nipa rironu nipa ẹsẹ mi?" Ṣugbọn ẹ wò ohun tí ó nsọ. Ó nsọ pé, Ó

kàn á mọ́ agbelebuu tí mi ò sì rù ú mọ́. Ọkàn mi, yin Oluwa, yin Oluwa.”

Ẹ sá tilẹ ronu nipa awọn ọrọ yẹn bí ẹ ti nkọ wọ́n lórin. Ẹ kọ ọ́ soke, a ó sì ṣetan fun

iwaasu yii.

Ẹṣẹ mi, ah ayọ pipé ti ironu ologo yii! Ẹsẹ mi, kí íṣe abala kan ṣugbọn gbogbo rẹ̀,

Ni a kàn mọ agbelebuu, mi ò sì rù ú mọ. Ọkàn mi, yin Oluwa, yin Oluwa!

Ó dara fun ọkan mi, Ó dara, ó dara, fun ọkan mi.

Oluwa, sì mú ọjọ tí igbagbọ mi yoo hàn yá kánkán,

Kí a ká awọsanma bí ẹni ká iwé; Ipè yoo tun dun, Oluwa yoo sì

sọkalẹ wá. Ani nitori naa, ó dara fun ọkan mi.

Ó dara, fun ọkàn mi. Ó dara, ó dara, fun ọkàn mi.

-

Bibeli diidi yè kooro nipa ọrọ igbala. Kò dá lori bí ó ti jẹ́ ẹni rere tó. Ọpọlọpọ eniyan

nrò pé awọn jẹ́ ẹni rere gan an pé awọn yoo sì dé ọrun nitori pé wọ́n jẹ́ ẹni rere gan an.

Ṣugbọn Bibeli wipe, Gbogbo eniyan li o sa ti ṣẹ ti wọn si ti kuna ogo Ọlọrun."

Bibeli wipe, “Kò si ẹnikan ti iṣe ododo, ko si ẹnikan." Emi ki iṣe olododo.

Ẹyin ki iṣe olododo. Tí ó bá jẹ́ pé ododo wa ni yoo gbé wa dé ọrun, kò

sí ẹnikan ninu wa ti yoo lọ.

. Gbà pé ẹlẹṣẹ ni ọ.

Bibeli tilẹ sọ ninu iwe Ifihan, ori ikọkanlelogun, ẹsẹ ikẹjọ pé:

(Ifihan :) Ṣugbọn awọn ojo, ati alaigbagbọ́, ati ẹni irira, ati apania, ati àgbèrè,

ati oṣó, ati abọriṣa, ati [ẹ fi eti silẹ̀ si eyi] - GBOGBO eke, ni yio ní ipa tiwọn

ninu adagun ina ti nfi iná ati sulfuru jò: eyi ti iṣe ikú keji.

Mo ti parọ́ rí. Gbogbo eniyan ni ó ti parọ́ rí. gbogbo wa ti ṣẹ̀, a ti ṣe nnkan

tí ó buru jù irọ pipa. Ẹ jẹ́ kí a sọ otitọ. Ọrun apaadi tọ́ sí gbogbo wa.

. Dá ijiya fun ẹsẹ mọ̀.

Ṣugbọn Bibeli wipe:

(Romu :) Ṣugbọn Ọlọrun fi ifẹ On papa si wa hàn ni eyi pe, nigbati awa jẹ ẹlẹṣẹ, Kristi

kú fun wa.

Nitori naa, Jesu Kristi, nitori pé Ó fẹ́ wa, Ó wá sí aye yii. bibeli wipe Ó jẹ́ Ọlọrun tí a fihan

ninu ara. Ọlọrun pilẹ̀ gbé awọ̀ eniyan wọ̀. Ó gbé igbe-aye ailẹṣẹ. Kò

dẹṣẹ kankan. Nitootọ, wọ́n nà Á tí wọ́n sì tutọ́ sí i lara tí wọ́n sì kàn á mọ́ agbelebuu.

Bibeli wipe nigba tí Ó wà lori agbelebuu yẹn, Òun funra Rẹ̀ rù ẹsẹ wa lara Rẹ̀ lori

igi naa. Nitori naa, gbogbo ẹṣẹ tí ẹ ti ṣẹ̀ rí, ẹṣẹ yoowu ti mo ti ṣẹ rí, nṣẹ ni ó dabi ẹni pe Jesu

ni ó dá a. A njẹ ẹ́ niya nitori ẹṣẹ wa. Nitootọ, wọ́n gbé oku Rẹ̀ nigba ti Ó

kú wọ́n sì sin Í sinu iboji, ẹmi Rẹ̀ sì lọ sí ipo-oku fun ọ̀sán mẹta ati

oru mẹta (Iṣe :). Lẹyin ọjọ mẹta, Ó tun jinde kuro ninu okú. Ó fi

iho ọwọ Rẹ̀ han awọn ọmọ ẹyin. Bibeli diidi yè kooro pé Jesu kú fun

gbogbo eniyan. Ó wipe Ó kú kì iṣe fun ẹṣẹ wa nikan, ṣugbọn fun ẹṣẹ gbogbo

aye. Ṣugbọn nnkan kan wà tí a gbọdọ ṣe ki a lè di ẹni igbala. Bibeli ní ibeere yẹn

ninu iwe Iṣe Awọn Aposteli, ori ikẹrindinlogun pé: Kinni kí emi ó ṣe kí nlè là? Wọn wi pe:

(Iṣe :-) "Gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ́, a o si gbà ọ là, iwọ ati awọn ará ile rẹ pẹlu.”

Oun sì niyẹn. Kò sọ pe, Darapọ mọ́ ijọ kan a ó sì gbà ọ́ là. Ṣe iribọmi

(Johannu :) Nitori Ọlọrun fẹ araye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bibi rẹ̀ kan ṣoṣo funni, ki ẹni

ti o ba gba a gbọ ma ba ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni iye ainipẹkun.

Ainipẹkun ntumọ̀ sí ainipẹkun. Ó ntumọ̀ sí ayeraye. Jesu wipe:

(Johannu :) Emi si fun wọn ni iye ainipẹkun; nwọn ki o si ṣegbe lailai; ko si

si ẹniti o le ja wọn kuro li ọwọ mi.

Bibeli nsọ ninu iwe Johannu ::

(Johannu :) Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gba mi gbọ, o ni iye ainipẹkun.

Nitori naa, tí ẹ ba gbà Jesu Kristi gbọ́, Bibeli yẹn nsọ pé ẹ ni iye ainipẹkun. Ẹ

ó yè titi aye. Ẹ kò lè padanu igbala yin. Ó jẹ́ ti ainipẹkun. Ó jẹ́ ti ayeraye.

Ní kete tí ẹ bá ti di ẹni igbala, ni kete tí ẹ ba ti gba A gbọ́, a ti gba yin là titi lae ohun yoowu,

ki o ṣẹlẹ ẹ kò lè padanu igbala yin laelae. bi mo tilẹ lọ dẹṣẹ buburu kan,

Ọlọrun yoo fi iyà rẹ̀ jẹ mi ni aye yii. Ti mo ba lọ pa ẹnikan lonii, Ọlọrun

yoo rí i daju pé mo jẹ iya rẹ̀. Ng ó lọ sí ẹ̀wọ̀n abi eyi ti ó buru ju bẹẹ abi kí n

gbà idajọ ikú, abi ohun yoowu ti aye yii nfi jẹ mi niya. Ọlọrun yoo rí i daju

pé ng ó jẹ iya abi ju bẹẹ lọ. Ṣugbọn mi ò ní lọ si ọrun apaadi. Kò sí nnkan

ti mo lè ṣe lati lọ si ọrun apaadi nitori pé a ti gba mi là. ti mo ba si lọ si ọrun apaadi, Ọlọrun ṣèké, nitori pe Ó

ṣeleri pé ẹnikẹni tí ó bá gbà Á gbọ́ ni iye ainipẹkun. Ó wipe:

(Johannu :) Ẹnikẹni ti o mbẹ lãye, ti o si gba mi gbọ, ki yio ku lailai.

Idi niyẹn ti a fi ri apẹẹrẹ awọn eniyan ninu Bibeli ti wọn ṣe ohun ti ó buru jọjọ

sibẹ, wọ́n dé ọ̀run. Bawo? Nitori pe wọn jẹ ẹni rere to bẹẹ? Rara. Ó rí bẹẹ nitori pe

wọn gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ. a dari ẹṣẹ wọn jì. Awọn eniyan miran ti wọn ti le gbé

igbe aye didara loju awọn eniyan, abi boya wọn tilẹ gbé igbe aye didara nitootọ, ṣugbọn

wọn kò gba Kristi gbọ, wọn yoo ni lati lọ si ọ̀run apaadi lati jiya fun

ẹṣẹ wọn.

. Ẹ fi ọkàn tán Kristi nikan gẹgẹ bi olugbala yin.

Ẹ sì jẹ́ ki ng sá pa ironu yii dé, nnkan kan ti mo fẹ rí i daju lati mú

jade lonii. Ibeere kan wà tí ọkan lara awọn ọmọ ẹyin Jesu beere. Ibeere yẹn

niyi: Ṣé awọn eniyan diẹ ni a gba? Ibeere daradara niyẹn, abi? Ṣe a gba awọn eniyan ti o pọju la?

Abi awọn eniyan diẹ ni a gbala? Tani ó nronu nihin pé awọn eniyan ti o pọju ni aye yii ni yoo lọ sí

ọ̀run? Ẹ fi inu rò ohun ti idahun naa jẹ́? Ó sọ ninu iwe matteu, ori keje pe:

(Matteu :-) Ẹ ba ẹnu-ọna hiha wọle; gboro li ẹnu-ọna na, ati onibu li

oju ọna na, ti o lọ sibi iparun; ọpọlọpọ li awọn ẹniti mba ibẹ wọle. Nitori pe hiha

ni ẹnu-ọna na, ati toro li oju-ọna na, ti o lọ si ibi iye, diẹ li awọn ẹniti o nrin

i.

Nigba naa ni ó tẹ siwaju lati sọ eyi:

(Matteu :-) Ki iṣe gbogbo ẹniti npe mi li Oluwa, Oluwa, , ni yio wọ

ijọba ọrun; bikoṣe ẹniti nṣe ifẹ ti ɓaba mi ti mbẹ li ọrun. Ọpọlọpọ enia ni yio

wi fun mi li ọjọ na pe, Oluwa, Oluwa, awa ko ha sọtẹlẹ li orukọ rẹ? ati orukọ rẹ

ki a fi le awọn ẹmi eṣu jade? ati li orukọ rẹ ki a fi ṣe ọpọ iṣẹ iyanu nla? Nigbana li emi o si wi

fun wọn pe, Emi ko mọ yin ri, ẹ kuro lọdọ mi, ẹnyin oniṣẹ ẹṣẹ.

Ṣaaju ohun gbogbo, awọn eniyan ti ó pọ julo ninu aye yii kò tilẹ sọ pé awọn gba jesu gbọ. A dupẹ,

awọn ti ó pọ julọ ninu yara ikẹkọọ yii nsọ pé awọn gba Jesu gbọ. Ṣugbọn awọn ti ó pọ julọ ninu aye kò

maa sọ pé awọn gba Jesu gbọ. Ṣugbọn Ọlọrun kilọ pé laaarin awọn ti wọ́n sọ pé awọn gba

Jesu gbọ, lara awọn ti wọn npe e ni Oluwa paapaa, ọpọ ni yoo maa wi pe, “A ṣe

gbogbo iṣẹ iyanu yii. Ki lo de ti a ko gba wa là?" Oun yoo wi pe, "Ẹ kuro lọdọ

mi, emi ko mọ yin ri.”Eyi yoo ri bẹẹ nitori pe igbala kì i ṣe nipa iṣẹ. Ti ẹ bá sì

gbarale iṣẹ ọwọ yin lati gba yin la, ti ẹ ba ro pe ẹ nlọ si ọrun nitori pe ẹ ti

ṣe iribọmi, abi ẹ lero pe “Ó dara, mo lero pe ẹ ni lati gbe igbe-aye rere. Mo lero

pe ẹ ni lati pa awọn ofin mọ lati di ẹni igbala. Mo lero pe ẹ ni lati lọ si ile ijọsin. Mo lero pe

ẹ ni lati yipada kuro ninu ẹṣẹ yin…” Ti ẹ ba ngbarale iṣẹ yin, Jesu

yoo sọ fun yin lọjọ kan pe, “Ẹ kuro lọdọ mi, emi ko mọ yin ri." Ẹ ni lati

fi gbogbo igbagbọ yin sinu ohun ti o ṣe. Ẹ ni lati fi igbagbọ yin sinu ohun ti Jesu ṣe ni

ori agbelebuu, nigba ti ó kú fun yin ti a sì sin ín ti ó si tun pada jinde. Iyẹn ni iwe irinna yin

sí ọ̀run. Ti ẹ ba ngbarale pé, “Ah, mo nlọ si ọ̀run nitori pe mo jẹ́

Kristiẹni rere to bẹẹ ti mo sì nṣe gbogbo nnkan iyanu wọnyi,” oun yoo wipe, “Ẹ kuro lọdọ mi.”

Ẹ si kiyesi ohun ti Ó sọ pé: “Ẹ kuro lọdọ mi, emi kò mọ yin RI.” Ki i ṣe pe, “Mo mọ yin

tẹlẹ.” Nitori pe bi O ba ti le mọ yin, bi mo ti mẹnuba tẹlẹ, ti ayeraye ni. Titi lae ni.

Bi Ó ba ti le mọ yin, a ti gba yin la titi laelae. Ṣugbọn Oun yoo wi pe, Ẹ kuro lọdọ mi,

Emi ko mọ yin ri.” Bi ẹ ba lọ si ọ̀run apaadi, a jẹ́ nitori pé ko mọ yin ri ni. Bi Ó ba ti lè mọ yin,

Ó ti mọ yin niyẹn. Nṣe ni ó dabi ẹni pe awọn ọmọ mi yoo maa jẹ ọmọ mi sibẹ. nigba ti ẹ bá

di atunbi, nigba ti ẹ ba jẹ ọmọ Rẹ, ẹ ó maa jẹ ọmọ Rẹ sibẹ. Ẹ le jẹ

ẹni ti ó nba orukọ ẹbi jẹ. Ẹ le jẹ ẹni ti Ọlọrun nba wi gidigidi laye yii.

Ẹ lè ṣe aye yin baṣu-baṣu nihin, ṣugbọn ẹ kò lè ṣe iyẹn bẹẹ. a gba yin la.

Àṣepari ni. nitori naa, eyi ni nnkan pataki ti mo fẹ fun yin nipa

igba ikẹyin. A ṣì tun ni iṣẹju diẹ fun ibeere nipa igbala abi nipa

igba ikẹyin.

Jesu mi Ọ̀wọ́n, mo mọ pe ẹlẹṣẹ ni mi. Mo mọ pe ó tọ́ ki nlọ si ọrun apaadi, ṣugbọn mo gbagbọ

pé o kú fun mi lori agbelebuu ti o si pada jinde. Jọwọ gba mi la nisisiyi ni agbatan ki o si fun mi ni

iye ainipẹkun. Iwọ nikan ni mo ngbarale, Jesu. Amin.

 

 

 

mouseover